ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 4/15 ojú ìwé 32
  • Àlàáfíà Kárí Ayé—Ibo Ni Yóò Ti Wá?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àlàáfíà Kárí Ayé—Ibo Ni Yóò Ti Wá?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 4/15 ojú ìwé 32

Àlàáfíà Kárí Ayé—Ibo Ni Yóò Ti Wá?

MÍMÚ ẹ̀kọ́ ìwé àti tẹ̀sìn tàn ká gbogbo ayé yóò ha mú àlàáfíà kárí ayé wá bí? Èrò Ọ̀mọ̀wé Robert Muller nìyẹn, igbá kejì akọ̀wé àgbà fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tẹ́lẹ̀, tó sì tún gba Ẹ̀bùn Ẹ̀yẹ UNESCO fún Ẹ̀kọ́ Àlàáfíà lọ́dún 1989. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Vancouver Sun ṣe sọ, Ọ̀mọ̀wé Muller “sọ ọ́ gbangba pé ó yẹ kí a kọ́ gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ lágbàáyé ní ọ̀wọ́ òkodoro àti ìlànà nípa pílánẹ́ẹ̀tì, kí a kọ́ wọn nípa ẹ̀dá ènìyàn àti àlàáfíà.” Ọ̀mọ̀wé ọ̀hún ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ kan tí gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó wà lágbàáyé yóò máa kọ́ àwọn ọmọ pé, àjọ UN ni ìrètí tó dára jù lọ fún àlàáfíà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Sun ti sọ ọ́, ó tún gbà gbọ́ pé “gbogbo ẹ̀sìn tó wà lágbàáyé ló yẹ kó di mẹ́ńbà àjọ tuntun kan tó fẹ́ fara jọ àjọ UN, èyí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìparapọ̀ Àwọn Ẹ̀sìn.” Nígbà náà, “gbogbo ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn ni yóò gbé àlàáfíà lárugẹ.”

Àlàáfíà kárí ayé yóò ha ṣeé ṣe ní tòótọ́? Ó dájú! Àmọ́ ṣá o, kò ní jẹ́ látọwọ́ ètò àjọ kan téèyàn gbé kalẹ̀. Ní ohun tó lé ní ẹgbàá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọdún [2,700] sẹ́yìn, akọ̀wé kan tí a mí sí fi orísun ẹ̀kọ́ àlàáfíà tó pegedé hàn nígbà tó sọ tẹ́lẹ̀ pé ‘láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni a óò ti kọ́’ àwọn èèyàn olóòótọ́ ọkàn, àlàáfíà wọn yóò sì pọ̀ “yanturu.”—Aísáyà 54:13.

Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ló “ń fúnni ní àlàáfíà.” (Róòmù 16:20) Àní nísinsìnyí pàápàá, àgbàyanu ẹ̀kọ́ tó kárí ayé ń lọ lọ́wọ́, bí Jèhófà ti ń kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ láti “wá àlàáfíà, kí [wọ́n] sì máa lépa rẹ̀,” kí wọ́n “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀,” kí wọ́n má sì “kọ́ṣẹ́ ogun jíjà mọ́.”—1 Pétérù 3:11; Aísáyà 2:2-4.

Ìjọsìn tí a gbé karí òtítọ́, tí kò ní àgàbàgebè àti ẹ̀tàn nínú, ni Ọlọ́run fọwọ́ sí, tí ó sì ń bù kún. (Mátíù 15:7-9; Jòhánù 4:23, 24) Kìkì ìjọsìn tòótọ́ nìkan, tó wà níbàámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló lè mú àwọn èèyàn tí ń gbé ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan, tí wọ́n sì ní ojúlówó ìfẹ́ sí ara wọn jáde.—Jòhánù 13:35.

Láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa àlàáfíà kárí ayé, a rọ̀ ọ́ pé kí o kàn sí àwọn tí ń tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́