ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 4/15 ojú ìwé 30
  • Ìwọ́ Ha Rántí Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ́ Ha Rántí Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?
    Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?
  • Ọjọ́ Ìgbàlà Nìyí!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Jésù Ń gbani Là—Lọ́nà Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 4/15 ojú ìwé 30

Ìwọ́ Ha Rántí Bí?

Ǹjẹ́ o mọrírì kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tóò, wò ó bí o bá lè dáhùn àwọn ìbéèrè díẹ̀ wọ̀nyí:

◻ Èé ṣe tí gbólóhùn náà tí Pọ́ọ̀lù sọ “ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi” fi jẹ́ èyí tó bá a mu wẹ́kú fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró? (2 Kọ́ríńtì 5:20)

Láyé àtijọ́, àwọn ikọ̀ ni a sábà máa ń rán nígbà tí gbúngbùngbún bá wáyé, láti rí i bóyá ogun ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. (Lúùkù 14:31, 32) Níwọ̀n bí aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ ti di àjèjì sí Ọlọ́run, ó ti rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ ẹni àmì òróró láti lọ sọ fún àwọn ènìyàn nípa àwọn ohun tí a lànà sílẹ̀ fún ìpadàrẹ́, ó rọ̀ wọ́n láti wá àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run.—12/15, ojú ìwé 18.

◻ Àwọn ohun mẹ́rin wo ló fún ìgbàgbọ́ Ábúráhámù lókun?

Èkíní, ó fi ìgbàgbọ́ tí ó ní nínú Jèhófà hàn nípa kíkọbi ara sí Ọlọ́run nígbà tí ó bá a sọ̀rọ̀ (Hébérù 11:8); èkejì, ìgbàgbọ́ rẹ̀ so mọ́ ìrètí rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí (Róòmù 4:18); ẹ̀kẹta, Ábúráhámù sábà máa ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀; àti ẹ̀kẹrin, Jèhófà ti Ábúráhámù lẹ́yìn nígbà tó tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí ó fún un. Àwọn ohun kan náà wọ̀nyí lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun lónìí.—1/1, ojú ìwé 17, 18.

◻ Kí ni gbólóhùn náà, “Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò,” túmọ̀ sí? (Mátíù 6:13)

A ń bẹ Ọlọ́run pé kí ó máà jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa yẹ̀ nígbà tí a bá dán wa wò láti ṣàìgbọràn sí i. Jèhófà lè tọ́ wa sọ́nà tí a kò fi ní juwọ́ sílẹ̀, tí Sátánì, “ẹni burúkú náà,” kò fi ní rí wa gbéṣe. (1 Kọ́ríńtì 10:13)—1/15, ojú ìwé 14.

◻ Kí ni ẹnì kan gbọ́dọ̀ ṣe bó bá fẹ́ rí ìdáríjì Ọlọ́run gbà fún àṣìṣe kan?

A gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run pẹ̀lú ìròbìnújẹ́ ọkàn àti “àwọn èso tí ó yẹ ìrònúpìwàdà.” (Lúùkù 3:8) Ẹ̀mí ìrònúpìwàdà àti ìfẹ́ láti ṣàtúnṣe yóò súnni láti wá ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí lọ́dọ̀ àwọn Kristẹni alàgbà. (Jákọ́bù 5:13-15)—1/15, ojú ìwé 19.

◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ ká sapá láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

Onírẹ̀lẹ̀ máa ń mú sùúrù, ó sì máa ń pa nǹkan mọ́ra, kì í ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yóò jẹ́ kí o ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tó nífẹ̀ẹ́ rẹ. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó ń mú ìbùkún Jèhófà wá. (Òwe 22:4)—2/1, ojú ìwé 7.

◻ Ìyàtọ̀ tó pe àfiyèsí wo ló wà láàárín ikú Jésù àti ti Ádámù?

Ikú tọ́ sí Ádámù, torí pé ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ni. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ikú kò tọ́ sí Jésù rárá, torí pé “kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.” (1 Pétérù 2:22) Fún ìdí yìí, nígbà tí Jésù kú, ó ní ohun kan tí ìtóye rẹ̀ pabanbarì, èyí tí Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀ kò ní nígbà ikú rẹ̀—ẹ̀tọ́ sí ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé. Nípa báyìí, ikú Jésù ní ìtóye ẹbọ tó ṣeé fi ra aráyé padà.—2/15, ojú ìwé 15, 16.

◻ Nínú ìran alásọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì rí, kí ni ìlú ńlá náà ń ṣàpẹẹrẹ?

Níwọ̀n bí ìlú ńlá náà ti wà ní àárín ilẹ̀ tí a sọ di àìmọ́, ó ní láti jẹ́ ohun kan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, ó dà bí ẹni pé ìlú ńlá náà ń ṣàpẹẹrẹ ìṣètò lórí ilẹ̀ ayé, tí ó ń mú àǹfààní wá fún gbogbo àwọn tí ó para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn olódodo lórí ilẹ̀ ayé.—3/1, ojú ìwé 18.

◻ Èé ṣe tí Jésù fi wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣayẹyẹ Ìrékọjá lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa?

Kì í ṣe pé Jésù ń dá ààtò ẹsẹ̀ fífọ̀ sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń ran àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́wọ́ láti ní ojú ìwòye tuntun—ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmúratán láti ṣe iṣẹ́ ìrẹ̀lẹ̀ jù lọ fún àwọn arákùnrin wọn.—3/1, ojú ìwé 30.

◻ Nígbà táa bá ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́, kí ló tún ṣe pàtàkì ju agbára àbínibí?

Àwọn ànímọ́ táa ní àti àwọn ìwà tẹ̀mí táa ti mú dàgbà, tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè fara wé. (Lúùkù 6:40; 2 Pétérù 3:11)—3/15, ojú ìwé 11, 12.

◻ Báwo ni àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ní gbangba ṣe lè mú kí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ka Ìwé Mímọ́ túbọ̀ jáfáfá?

Nípa ṣíṣe ìfidánrawò. Bẹ́ẹ̀ ni, nípa kíkàwé sókè léraléra títí wọn yóò fi lè kà á lọ́nà tó já gaara. Bí àwọn kásẹ́ẹ̀tì táa ká Bíbélì sínú rẹ̀ bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó lédè rẹ, ó dára láti fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ tí òǹkàwé náà tẹnu mọ́ àti bó ṣe ń yí ohùn padà, ó sì dára láti ṣàkíyèsí bó ṣe ń pe àwọn orúkọ àti ọ̀rọ̀ tó ṣàjèjì.—3/15, ojú ìwé 20.

◻ Báwo ni ‘ẹ̀mí ṣe ń padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run’ nígbà tí ẹnì kan bá kú? (Oníwàásù 12:7)

Níwọ̀n ìgbà tó ti jẹ́ pé ẹ̀mí ni agbára ìwàláàyè, ó “padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́” ní ti pé, láti ìgbà náà lọ, ọwọ́ Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ìrètí èyíkéyìí tí onítọ̀hún ní fún ọjọ́ ọ̀la wà. Ọlọ́run nìkan ṣoso ló lè dá ẹ̀mí, tàbí agbára ìwàláàyè náà padà, kí ó sì mú kí ẹni náà padà wà láàyè. (Sáàmù 104:30)—4/1, ojú ìwé 17.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́