ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 6/1 ojú ìwé 8
  • “Lọ́dọ̀ Ọlọ́run Ohun Gbogbo Ṣeé Ṣe”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Lọ́dọ̀ Ọlọ́run Ohun Gbogbo Ṣeé Ṣe”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Kún fun Ìmoore fun Itilẹhin Jehofa tí Kìí Kùnà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Sọ fún Wọn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Wọn
    Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • “Jèhófà, O Wá Mi Kàn!”
    Jí!—2004
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 6/1 ojú ìwé 8

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

“Lọ́dọ̀ Ọlọ́run Ohun Gbogbo Ṣeé Ṣe”

ÀWỌN ọ̀rọ̀ òkè yìí, tó wà nínú Mátíù 19:26, jẹ́ òótọ́ nínú ọ̀ràn ọ̀dọ́bìnrin kan ní Venezuela. Lẹ́yìn tó rí ìjẹ́pàtàkì gbígbáralé Jèhófà pátápátá, ló tó lè borí ìṣòro ńlá kan. Ó tẹnu bọ̀rọ̀, ó ní:

“Màámi àgbà lójú àánú gan-an, ó sì nífẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n ó dùn mí pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún péré ni mo jẹ́ nígbà tó kú. Ikú rẹ̀ gbò mí gan-an. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú ṣáá, débi pé kì í tilẹ̀ wù mí láti jáde lọ síta lọ ṣeré. Díẹ̀ ló kù kí n ya ara mi láṣo.

“N kò lọ iléèwé, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ wáṣẹ́ ṣe. Ṣe ni mo kàn jókòó pa sínú yàrá mi. Mo dá nìkan wà láìlọ́rẹ̀ẹ́, èyí sì fa ìsoríkọ́ gidi. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí wo ara mí bí aláìníláárí, mo sì fẹ́ kú, kí gbogbo ẹ̀ kúkú dópin. Mo wá ń bi ara mi ṣáá pé, ‘Èé ṣe tí mo fi wà láàyè?’

“Tẹ́lẹ̀ rí, màmá mi máa ń gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ́wọ́ ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gisela. Lọ́jọ́ kan, màmá mi tajú kán rí Gisela bó ti ń gba ẹ̀gbẹ́ ilé wa kọjá, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá yóò lè máa wá ràn mí lọ́wọ́. Gisela sọ pé òun á gbìyànjú, ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti yọjú sí i. Gisela kò tìtorí èyí juwọ́ sílẹ̀. Ó kọ lẹ́tà kan sí mi, ó sì sọ pé òun fẹ́ bá mi dọ́rẹ̀ẹ́, ó tún sọ pé ẹni pàtàkì kan, tó ṣe pàtàkì gidigidi ju òun lọ, fẹ́ bá mi dọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú. Ó sọ pé ẹni yẹn ni Jèhófà Ọlọ́run.

“Èyí wú mi lórí gan-an, mo sì fèsì lẹ́tà rẹ̀. Oṣù mẹ́ta la fi ń kọ lẹ́tà síra. Gisela rọ̀ mí tí-tí-tí, kó tó di pé ọkàn mi fẹ́ láti bá a pàdé lójúkojú. Nígbà táa kọ́kọ́ bára wa pàdé, Gisela kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì, ó lo ìwe náà Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ó ní kí n wá sípàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò. Ọkàn mi là gàrà. Mi ò tíì jáde nílé láti ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, àtirìn lójú títì sì ń dáyà já mi.

“Gisela mú sùúrù fún mi gan-an. Ó fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé kò sídìí fún jíjáyà àti pé a óò jọ lọ sípàdé náà ni. Mo wá gbà ṣá. Nígbà táa dé inú Gbọ̀ngàn Ìjọba, ṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀nrìrì tí òógùn sì bò mí. Mi ò lè kí ẹnikẹ́ni. Síbẹ̀síbẹ̀, mo gbà pé mi ò ní ṣíwọ́ lílọ sípàdé, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ sì ni Gisela máa ń wá mú mi lọ láìkùnà.

“Kí n lè borí ojora tó máa ń mú mi, Gisela máa ń rí sí i pé a tètè dépàdé. A óò wá dúró sẹ́nu ọ̀nà, a ó sì máa kí gbogbo èèyàn bí wọ́n ti ń dé. Lọ́nà yẹn, èèyàn kọ̀ọ̀kan tàbí méjìméjì ni mo máa ń dojú kọ lẹ́ẹ̀kan, dípò dídojúkọ gbogbo àwùjọ lẹ́ẹ̀kan náà. Nígbà tí mo nímọ̀lára pé ó ti wá dójú ẹ̀ wàyí, Gisela fa ọ̀rọ̀ inú Mátíù 19:26, yọ fún mi, tó kà pé: ‘Lọ́dọ̀ ènìyàn, èyí kò ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.’

“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, nígbà tó yá ṣá, mo wá lè lọ sí ìpéjọpọ̀ ńlá pàápàá, nígbà àpéjọ àyíká. Ẹ wo irú ìgbésẹ̀ ńlá tí ìyẹn jẹ́ fún mi! Ní September 1995, mo gbọ́kàn ìgboyà wọ̀, mo lọ bá àwọn alàgbà, mo sì sọ fún wọn pé mo fẹ́ máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé. Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, ní April 1996, ni mo fẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi sí Jèhófà hàn nípa ìbatisí nínú omi.

“Nígbà tẹ́nì kan bi mí lẹ́nu àìpẹ́ yìí nípa bí mo ṣe ní ìgboyà láti gbé ìgbésẹ̀ yìí, mo fèsì pé: ‘Ìfẹ́ mi láti mú inú Jèhófà dùn ga ju ẹ̀rù tí ń bà mí.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń sorí kọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n sísìn tí mo ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà ń mú kí ayọ̀ mi kún sí i. Nígbà tí mo bá wẹ̀yìn wò, mo ní láti fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú Gisela. Wàyí o, mo ní Ọ̀rẹ́ kan tó fẹ́ràn mi, tó sì “ń fi agbára fún mi.’”—Fílípì 4:13.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

“Ìfẹ́ mi láti mú inú Jèhófà dùn ga ju ẹ̀rù tí ń bà mí”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́