Ohun Kan Tó Sàn Ju Èròjà Ìṣaralóge
LẸ́YÌN títọ́ka sí “àwọn èròjà àfiṣọ̀ṣọ́” táwọn obìnrin fi ń bẹwà kún ara wọn, àpọ́sítélì Pétérù gbani nímọ̀ràn pé: “Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kí ẹwà yín jẹ́ ti ẹni náà gan-an tí ẹ jẹ́ nínú lọ́hùn-ún, ẹwà tí kì í ṣá ti ẹ̀mí tútù àti ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, ẹwà tó ṣeyebíye jù lọ lójú Ọlọ́run.”—1 Pétérù 3:3, 4, Today’s English Version.
Ó dára láti mọ̀ pé nígbà tí àpọ́sítélì náà kọ̀wé nípa irú ọ̀ṣọ́ òde ara bẹ́ẹ̀, ó lo irú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, koʹsmos, èyí sì ni ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà “cosmetic,” tó túmọ̀ sí “ohun ìṣaralóge, pàápàá ti àwọ̀ ara.” Ṣé ohun tí Pétérù ń sọ ni pé àwọn obìnrin Kristẹni kò gbọ́dọ̀ lo àwọn èròjà ìṣaralóge àti àwọn nǹkan mìíràn táa fi ń bẹwà kún ara? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò sọ nǹkan kan tó jọ bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fàyè sílẹ̀ kí kálukú ṣèpinnu tirẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí, nítorí náà, a lè retí kí ìyàtọ̀ wà nínú èyí táwọn kan lè fẹ́ láti lò.
Ṣùgbọ́n, báa bá ṣàṣejù nínú lílo èròjà ìṣaralóge, tàbí táa ṣe é dé ìwọ̀n tó fi ń kọ àwọn èèyàn lóminú, èrò wo là ń gbìn sí wọn lọ́kàn? Kì í ha ṣe èrò pé a jẹ́ ẹni tó lajú sódì, ẹni tó bẹ, ológe àṣejù, aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀, tàbí ẹni tó jọra rẹ̀ lójú jù? Ní tòótọ́, ó lè tàbùkù sí ìrísí obìnrin kan, bóyá kó fúnni ní èrò òdì nípa ìwà rere rẹ̀.—Fi wé Ìsíkíẹ́lì 23:36-42.
Fún ìdí yìí, bí obìnrin “tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé [òun] ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run” bá yàn láti lo àwọn èròjà aṣaralóge, yóò sapá láti rí i pé ojú òun fi hàn pé èrò inú òun yè kooro, pé òun ní ìwà pẹ̀lẹ́, inú rere, àti pé òun jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì. Irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ yóò fi kún ọlá àti ẹwà rẹ̀. Àní, yálà ó yàn láti lo àwọn èròjà ìṣaralóge tàbí kò lò ó, yóò ní iyì àti ẹwà ti inú. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Pétérù táa fà yọ lókè yìí ti wí, èyí yóò fi hàn pé ó mọ̀ pé ohun kan wà tó sàn ju èròjà ìṣaralóge.—1 Tímótì 2:9, 10.