O Lè Mọ Ọjọ́ Ọ̀la!
Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ló máa ń ronú gan-an nípa ọjọ́ ọ̀la. Wọ́n máa ń fẹ́ láti wéwèé, kí wọ́n fi ọgbọ́n dókòwò, wọ́n sì máa ń fẹ́ kí ọkàn àwọn balẹ̀. Àmọ́, ṣé ọ̀nà kan tiẹ̀ wà táa fi lè ní ìdánilójú nípa bí ọjọ́ ọ̀la yóò ṣe rí?
NÍBI táwọn èèyàn ti ń ṣèwádìí bí ọjọ́ ọ̀la yóò ṣe rí kiri, onírúurú nǹkan ni wọ́n ti lò. Àwọn onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, ìyẹn àwọn tí a ń pè ní olùṣàyẹ̀wò ọjọ́ ọ̀la ti gbé àwọn àṣà tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí yẹ̀ wò, orí àwọn àṣà náà ni wọ́n sì gbé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọn kà. Bákan náà làwọn onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ń ṣe ní ẹ̀ka tiwọn. Àwọn awòràwọ̀ àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́ ń lo àwọn àwòrán ìràwọ̀, wọ́n ń lo àwo ribiti tí wọ́n fi ń woṣẹ́ àti àwọn nǹkan míì tó rúni lójú, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ń gbà wọ́n gbọ́. Fún àpẹẹrẹ, òkìkí Nostradamus, awòràwọ̀ tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé nì, ṣì ń kàn títí di ìsinsìnyí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ti kọjá tó ti kú.
Gbogbo àwọn aláfẹnujẹ́ wòlíì wọ̀nyí ni ẹ̀rí ti fi hàn pé wọn ò ṣeé gbára lé, tí wọ́n sì ti já ọ̀pọ̀ èèyàn kulẹ̀. Èé ṣe? Nítorí pé wọ́n kọ Jèhófà Ọlọ́run àti Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, sílẹ̀. Ìdí nìyẹn tí wọn ò fi lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó ṣe kókó bí ìwọ̀nyí: ‘Báwo ló ṣe lè dá mi lójú pé àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ yóò ní ìmúṣẹ? Báwo ni wọ́n ṣe bá ète tí Ọlọ́run ní fún ìran ènìyàn mu? Báwo ní èmi àti ìdílé mi ṣe lè jàǹfààní nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí?’ Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
Ọ̀pọ̀ ọ̀nà mìíràn ni àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tún fi níye lórí ju àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn lọ. Lọ́nà tó yàtọ̀ sí àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn awòràwọ̀ máa ń sọ, ó fúnni ní òmìnira láti yan ohun tó wuni. Nípa bẹ́ẹ̀, kò fi ẹnikẹ́ni sábẹ́ kádàrá. (Diutarónómì 30:19) Irú àwọn ìwé tí Nostradamus kọ jẹ́ èyí tí kò kọ́ni ní ẹ̀kọ́ ìwà rere kankan, wọ́n sì fi ohun tó rúni lójú àti àwọn ohun tó lè tètè mú kí èèyàn fẹ́ wá fìn-ín ìdí kókò ṣe bojúbojú. Ṣùgbọ́n àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ní àwọn ìlànà ìwà rere tó dúró gbọn-in. Ó ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run yóò fi ṣe ohun tó ti pète. (2 Kíróníkà 36:15) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà kò sì lè kùnà láé, nítorí pé “Ọlọ́run . . . kò lè purọ́.” (Títù 1:2) Abájọ tí àwọn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń tọ́ sọ́nà fi ń gbé ìgbésí ayé ẹni tí ó jẹ́ olóye, ìgbésí ayé tó ní ète, tó sì jẹ́ aláyọ̀, abájọ tí wọn kì í fi àkókò wọn àti ohun ìní wọn ṣòfò sórí àwọn nǹkan tí kò ní láárí.—Sáàmù 25:12, 13.
Ìwọ̀nyí àti ọ̀pọ̀ àwọn kókó mìíràn la jíròrò ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” ti ọdún 1999 sí 2000, èyí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe jákèjádò ayé. Àwọn àsọyé, ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò, àṣefihàn, àti àwòkẹ́kọ̀ọ́ kan láti inú Bíbélì pé àfiyèsí àwùjọ sí àgbàyanu ogún tẹ̀mí tí àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń fi í sílò ń gbádùn. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn kókó pàtàkì táa gbádùn ní àpéjọpọ̀ náà.