Àkókò Láti Sọ̀rọ̀ Àṣírí Síta
Pípa àwọn ọ̀ràn kan mọ́ láṣìírí lè mú kó ṣeé ṣe láti pa àlàáfíà mọ́. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ àkókò kankan wà tá a lè sọ̀rọ̀ àṣírí síta? Kíyè sí ohun tí wòlíì Ámósì wí nípa Ọlọ́run rẹ̀: “Jèhófà . . . kì yóò ṣe ohun kan láìjẹ́ pé ó ti ṣí ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.” (Ámósì 3:7) Látinú ọ̀rọ̀ yìí, a lè rí ẹ̀kọ́ kan kọ́ nípa ọ̀ràn àṣírí. Jèhófà lè pa àwọn ọ̀ràn kan mọ́ láṣìírí fún sáà kan, kí ó sì wá ṣí i payá fún àwọn kan nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà nínú ọ̀ràn yìí?
Nígbà mìíràn, àwọn olùṣọ́ àgùntàn tá a yàn nínú ìjọ Kristẹni lè rí i pé ó ṣàǹfààní láti pa ọ̀ràn kan mọ́ láṣìírí. (Ìṣe 20:28) Bí àpẹẹrẹ, fún ire ìjọ, wọ́n lè pinnu pé àwọn ò ní sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ìṣètò kan tàbí kí wọ́n pa àwọn ìyípadà kan nínú ọ̀ràn ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ mọ́ láṣìírí fún sáà kan.
Àmọ́, nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ káwọn tí ọ̀ràn náà kàn mọ̀ bóyá a ó sọ ọ̀ràn náà síta, kí a sì sọ ìgbà tí a ó sọ ọ́ síta àti bí a ó ṣe sọ ọ́. Mímọ ìgbà tí a ó sọ ọ̀ràn kan síta lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa àṣírí mọ́.—Òwe 25:9.