Akitiyan Tó Ń Gbé Ìlànà Ìwà Rere Ga
Ní apá ìparí ọdún 2001, àwọn tó ṣí rédíò wọn sí Ilé Iṣẹ́ Rédíò Mòsáńbíìkì gbọ́ ìkéde yìí:
“Ààrẹ orílẹ̀-èdè yìí ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Maputo. Ó gba ìjọ yìí níyànjú láti má ṣe dẹwọ́ akitiyan tí wọ́n ń ṣe láti mú kí ìlànà ìwà rere láàárín ìdílé túbọ̀ dára sí i kí wọ́n má sì dẹwọ́ ìsapá tí wọ́n ń ṣe láti mú kí àwọn àgbàlagbà mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá èèyàn ló ti jàǹfààní ètò yìí. Gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Chissano ti sọ, ó yẹ ká gbóríyìn fáwọn ètò bí èyí nítorí àǹfààní tí wọ́n ń ṣe fún àwùjọ, ò kéré tán, nínú yíyanjú ìṣòro àìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà tó ń bá orílẹ̀-èdè yìí fínra.”
Ìkéde náà wá gbé díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ tí ààrẹ sọ tí wọ́n gbà sílẹ̀ jáde, ó lọ báyìí: “Ó ń wú wa lórí gan-an láti rí bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe fẹ́ láti mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà. Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn aráàlú máa ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí iye àwọn tó mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà túbọ̀ pọ̀ sí i. Nítorí náà, màá fẹ́ láti gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níyànjú pé kí wọ́n má dẹwọ́ ètò mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà tí wọ́n ń ṣe, ní èdè èyíkéyìí tó wù ó jẹ́. Ohun tó jà jù ni pé káwọn èèyàn ti mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà kí wọ́n lè bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ fàlàlà kí wọ́n sì lè túbọ̀ kópa nínú ètò ẹ̀kọ́ lọ́jọ́ iwájú.”
Ibi ẹgbẹ̀rin ó lé àádọ́ta [850] làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mòsáńbíìkì ti ń darí ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà náà kó lè ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti fúnra wọn máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n tún ń darí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Gbogbo èyí jẹ́ apá kan ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé tó ti dé igba ó lé márùnlélọ́gbọ̀n [235] ilẹ̀ báyìí. (Mátíù 24:14) Ìwọ náà lè jàǹfààní nínú ètò yìí. Jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àdúgbò rẹ.