ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 9/15 ojú ìwé 32
  • Ìgbà Tí Àwọn Èèyàn Yóò Máa Mú Ìlérí Wọn Ṣẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Tí Àwọn Èèyàn Yóò Máa Mú Ìlérí Wọn Ṣẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 9/15 ojú ìwé 32

Ìgbà Tí Àwọn Èèyàn Yóò Máa Mú Ìlérí Wọn Ṣẹ

MÉLÒÓ la fẹ́ kà nínú àwọn ìlérí táwọn èèyàn ti ṣe àmọ́ tí wọn ò mu ṣẹ. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn kò ní jagun kò mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ, tí wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ kógun tó gbóná janjan ja àwọn èèyàn wọn. Napoleon sọ nígbà kan pé: “Kìkì ìgbà tí wọ́n bá fúngun mọ́ àwọn alákòóso ni wọ́n tó máa ń ṣe ohun tí wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́, tàbí nígbà tí wọ́n bá rí i pé nǹkan á ṣẹnuure fún wọn níbẹ̀.”

Ìlérí táwọn èèyàn ń ṣe náà ńkọ́? Ó máa ń dunni wọra tẹ́nì kan bá ṣèlérí fúnni àmọ́ tí kò mú ìlérí náà ṣẹ! Àgàgà tó bá lọ jẹ́ ẹni tó o mọ̀ tó o sì gbọ́kàn lé lẹni náà. Àmọ́, ó lè jẹ́ pé òde tí ò dẹrùn fún àwọn èèyàn ni ò jẹ́ kí wọ́n lè mú ìlérí wọn ṣẹ tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ni wọn ò fẹ́ ṣe ohun tí wọ́n ti ṣèlérí.

Ẹ ò rí i pé ìyàtọ̀ ńláǹlà ló wà láàárín ìlérí táwọn ẹ̀dá èèyàn máa ń ṣe àtèyí tí Ọlọ́run máa ń ṣe! Àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣeé gbọ́kàn lé kò sì sí ìjákulẹ̀ kankan níbẹ̀. Ìlérí èyíkéyìí tí Jèhófà Ọlọ́run bá ṣe máa nímùúṣẹ ṣáá ni. Kò sóhun tó lè yẹ̀ ẹ́. Ìwé Aísáyà 55:11 sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ awíbẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀ nípa àwọn Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí. Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”

Nígbà náà, irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì? A lè gbọ́kàn lé wọn dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:3, 4) O lè gbádùn irú àwọn ìbùkún báwọ̀nyí tó o bá ṣe ohun tí Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́