ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 12/15 ojú ìwé 32
  • Ǹjẹ́ Ohun Ìyanu Máa Ń jọ ọ́ Lójú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ohun Ìyanu Máa Ń jọ ọ́ Lójú?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 12/15 ojú ìwé 32

Ǹjẹ́ Ohun Ìyanu Máa Ń jọ ọ́ Lójú?

ǸJẸ́ o ṣàkíyèsí pé tí àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run àtàwọn ànímọ́ rẹ̀, wọ́n máa ń sọ ọ́ lọ́nà tó fi hàn pé ohun ìyanu jọ wọ́n lójú? Onísáàmù náà sọ pé: “A ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.” (Sáàmù 139:14) Wòlíì Aísáyà kọ̀wé pé: “Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run mi. Mo gbé ọ ga, mo gbé orúkọ rẹ lárugẹ, nítorí pé o ti ṣe àwọn ohun àgbàyanu.” (Aísáyà 25:1) Tàbí kẹ̀, ronú lórí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó fi hàn pé ohun ìyanu jọ ọ́ lójú àti pé ohun ìyanu ń mú kó ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀, ó ní: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o!”—Róòmù 11:33.

Ìwé atúmọ̀ èdè náà The Oxford Encyclopedic English Dictionary sọ pé ọ̀rọ̀ náà “ìyanu” túmọ̀ sí “bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa nígbà tá a bá rí nǹkan tí a kò retí tẹ́lẹ̀ tàbí nǹkan tó ṣàjèjì sí wa tàbí ohun tá ò mọ bó ṣe jẹ́, pàápàá ìyàlẹ́nu tá a máa ń ní nítorí nǹkan tá a rí tó jọ wá lójú tàbí nǹkan tó mú ká ní ẹ̀mí ìtọpinpin àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.”

Nígbà tí àwọn ọmọdé bá rí nǹkan kan tàbí tí wọ́n fọwọ́ kan nǹkan kan tàbí tí wọ́n gbọ́ nǹkan tó jẹ́ tuntun sí wọn, ǹjẹ́ kì í dùn mọ́ wa láti rí bí wọ́n ṣe máa ń ranjú mọ́ nǹkan ọ̀hún nítorí pé ó jọ wọ́n lójú? Ó dun ni pé bí wọ́n ṣe ń dàgbà sí i, ohun ìyanu tó ń jọ wọ́n lójú tẹ́lẹ̀ rí nítorí ẹ̀mí ìtọpinpin tí wọ́n ní tàbí nítorí pé nǹkan ọ̀hún jẹ́ tuntun sí wọn, kì í jọ wọ́n lójú mọ́.

Àmọ́ ṣá o, ìbẹ̀rù àti ọ̀wọ̀ tí àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì tá a kọ ọ̀rọ̀ wọn síbí yìí ní jinlẹ̀ nínú ọkàn wọn. Ṣe ni ẹ̀mí rere yìí wà lára wọn títí lọ. Kí ló mú kó rí bẹ́ẹ̀? Ohun tó mú kí ohun ìyanu máa jọ wọ́n lójú ni pé wọ́n máa ń ronú jinlẹ̀ lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run. Onísáàmù náà gbàdúrà pé: “Mó ṣàṣàrò nípa ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, mo ronú lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ; ohun ìyanu ńláǹlà ti ìṣẹ̀dá rẹ gbà mí lọ́kàn.”—Sáàmù 143:5, The New English Bible.

Ó mà dára gan-an o pé ohun ìyanu máa ń jọ àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run lóde òní lójú! Ǹjẹ́ ó ń jọ ìwọ náà lójú? Ǹjẹ́ ò ń ronú jinlẹ̀ lórí ohun ìyanu?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́