ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 7/1 ojú ìwé 32
  • Lẹ́tà Tí Ọmọbìnrin Kan Kọ sí Nóà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lẹ́tà Tí Ọmọbìnrin Kan Kọ sí Nóà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 7/1 ojú ìwé 32

Lẹ́tà Tí Ọmọbìnrin Kan Kọ sí Nóà

“NÓÀ mi ọ̀wọ́n, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti ka ìtàn rẹ nínú Bíbélì, mo sì kà nípa bó o ṣe kan ọkọ̀ áàkì tó gba ìwọ àti ìdílé rẹ̀ là nígbà Ìkún Omi.”

Bí ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Minnamaria ṣe bẹ̀rẹ̀ lẹ́tà rẹ̀ nìyẹn. Ó kọ lẹ́tà náà nígbà ìdíje ìwé kíkọ tí wọ́n ṣe fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́rìnlá sí mọ́kànlélógún. Àwọn tí wọ́n ṣètò ìdíje náà ni iléeṣẹ́ ìfìwéránṣẹ́ ilẹ̀ Finland, Ẹgbẹ́ Àwọn Olùkọ́ Èdè Ilẹ̀ Finland àti Ẹgbẹ́ Àwọn Òǹṣèwé Ilẹ̀ Finland. Wọ́n ní kí àwọn olùdíje kọ lẹ́tà kan tó dá lórí ìwé kan. Wọ́n lè kọ lẹ́tà náà sí ẹni tó ṣe ìwé ọ̀hún tàbí kí wọ́n kọ ọ́ sí ẹnì kan tí ìwé náà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àwọn olùkọ́ yan lẹ́tà tó lé ní egbèje [1,400] lára àwọn lẹ́tà táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kọ, wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ìdíje náà. Ìgbìmọ̀ yìí wá yan lẹ́tà kan tó dára jù lọ, wọ́n tún yan mẹ́wàá tó gba ẹ̀bùn ipò kejì, àti mẹ́wàá tó gba ẹ̀bùn ipò kẹta. Inú Minnamaria dùn pé lẹ́tà òun wà lára àwọn mẹ́wàá tó gba ẹ̀bùn ipò kẹta.

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Nóà tó gbé ayé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] ọdún sẹ́yìn ni Minnamaria, akẹ́kọ̀ọ́ tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún yìí kọ lẹ́tà tiẹ̀ sí? Ó sọ pé: “Ohun tó kọ́kọ́ wá sọ́kàn mi ni Bíbélì. Mo mọ ìtàn àwọn èèyàn inú Bíbélì dáadáa. Mo ti kà nípa wọn débi pé ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ṣì wà láàyè lójú mi. Nóà ni mo yàn láàyò nítorí pé ìgbésí ayé rẹ̀ wú mi lórí, ó sì yàtọ̀ sí tèmi.”

Ohun tí Minnamaria fi parí lẹ́tà tó kọ sí Nóà rèé, ó ní: “O ṣì jẹ́ àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn. Ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ jẹ́ ìṣírí fún gbogbo àwọn tí wọ́n ń ka Bíbélì pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wọn.”

Lẹ́tà tí ọ̀dọ́mọdé tó máa ń ka Bíbélì yìí kọ fi hàn kedere pé, lóòótọ́ ni Bíbélì “yè, ó sì ń sa agbára” lórí àwọn èèyàn àtèwe-àtàgbà.—Hébérù 4:12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́