Ǹjẹ́ Ìgbà Kan Tiẹ̀ Máa Wà Tá A Máa Ní Ààbò Tòótọ́?
INÚ àwọn ọmọ ń dùn bí wọ́n ṣe ń bá àwọn òbí wọn tó fẹ́ràn wọn ṣeré—ǹjẹ́ a rẹ́ni tínú rẹ̀ kì í dùn tó bá ń wo irú nǹkan bẹ́ẹ̀? Ọkàn irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ máa ń balẹ̀ dáadáa nítorí pé wọn wà lọ́dọ̀ àwọn òbí tó bìkítà nípa wọn. Àmọ́, agbára káká ni ọ̀pọ̀ ọmọdé fi láǹfààní àtigbádùn irú àkókò aláyọ̀ bẹ́ẹ̀. Dípò ìyẹn, ńṣe làwọn ọmọ kan máa ń fi ojoojúmọ́ ronú nípa báwọn ṣe máa ríbi sùn sí lálẹ́. Ǹjẹ́ ìrètí kankan tiẹ̀ wà fún irú àwọn ọmọ aláìnílé bẹ́ẹ̀ àtàwọn mìíràn tó ń gbé ayé láìsí ààbò kankan?
Bó tilẹ̀ dà bíi pé ọjọ́ ọ̀la ò ní dáa, síbẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa nírètí. Wòlíì Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ọjọ́ náà yóò dé nígbà tí gbogbo èèyàn yóò ní ààbò tòótọ́. Ó kọ̀wé pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ.”—Aísáyà 65:21, 22.
Ǹjẹ́ ìrètí yìí lẹ́sẹ̀ nílẹ̀? Ó ṣe tán, ọ̀rọ̀ náà “ìrètí” kì í fi gbogbo ìgbà túmọ̀ sí ohun tó dáni lójú. Bí àpẹẹrẹ, gbólóhùn kan tí wọ́n sábà máa ń sọ ní Brazil ni pé “Ìrètí kì í kú bọ̀rọ̀.” Tó túmọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń retí pé ohun kan ṣì lè dára nígbà tó sì jẹ́ pé nǹkan náà ò lè dára mọ́. Àmọ́, ìrètí tí Ọlọ́run alààyè jẹ́ ká ní yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kò sí ẹni tí ó gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lé [Ọlọ́run] tí a óò já kulẹ̀.” (Róòmù 10:11) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti nímùúṣẹ mú un dá wa lójú pe gbogbo àwọn ìlérí mìíràn tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe ní yóò nímùúṣẹ. Nígbà tó bá mú àwọn ìlérí yẹn ṣẹ, àwọn ipò tó ń mú káwọn ọmọdé máa fi ojú pópó ṣe ilé yóò di ohun àtijọ́.
Kódà lónìí pàápàá, àwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ tá a rí nínú Bíbélì lè ràn àwọn tí kò nírètí lọ́wọ́ láti mú kí ìgbésí ayé wọn túbọ̀ sunwọ̀n sí i kí wọ́n sì rí ààbò tòótọ́. Báwo nìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí.