Wọ́n Ń Pa Àwọn Arúgbó Tì, Wọ́n sì Ń Hùwà Ìkà sí Wọn
BÍ ỌLỌ́DẸ kan ṣe ń lọ káàkiri, ó ṣàdédé rí ohun ìyàlẹ́nu kan tó burú jáì. Òkú tọkọtaya kan ló rí níwájú ilé kan tó jẹ́ ilé olówó. Arúgbó ni wọ́n, ṣe ni wọ́n sì bẹ́ sílẹ̀ láti ojú fèrèsé ilé wọn alájà mẹ́jọ tí wọ́n sì kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé pípa tí wọ́n pa ara wọn yìí ya èèyàn lẹ́nu gan-an, ohun tó mú kí wọ́n pa ara wọn ló ya èèyàn lẹ́nu jù. Bébà tí wọ́n rí nínú àpò èyí ọkọ kà pé: “A para wa nítorí ìwà ìkà tí ọmọ wa àtìyàwó ẹ̀ ń hù sí wa àti bí wọ́n ṣe ń fòòró ẹ̀mí wa.”
Ohun táwọn arúgbó méjì yìí ṣe lè ṣàjèjì o, àmọ́ ohun tó mú wọn ṣe é ń ṣẹlẹ̀ káàkiri, ó sì ń ba ọ̀pọ̀ èèyàn nínú jẹ́. Káwọn èèyàn máa hùwà ìkà sáwọn arúgbó ti wà kárí ayé báyìí. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò:
• Ìwádìí fi hàn pé mẹ́rin nínú ọgọ́rùn-ún arúgbó ilẹ̀ Kánádà làwọn èèyàn ń hùwà ìkà sí tàbí tí wọ́n ń lù ní jìbìtì, àwọn ará ilé wọn ló sì sábà máa ń ṣe àìdáa yìí sí wọn. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ arúgbó ni ìtìjú tàbí ìbẹ̀rù kì í jẹ́ kí wọn sọ ohun tójú wọn ń rí. Àwọn ògbógi sọ pé ó ṣeé ṣe káwọn tọ̀ràn náà kàn gan-an tó bíi mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún.
• Ìwé ìròyìn India Today sọ pé: “Orílẹ̀-èdè Íńdíà táwọn èèyàn máa ń rò pé àwọn ẹbí ti sún mọ́ra wọn gan-an kò tún rí bẹ́ẹ̀ mọ́ báyìí nítorí ńṣe làwọn arúgbó táwọn ọmọ wọn kò tọ́jú mọ́ túbọ̀ ń pọ̀ sí i.”
• Àkọsílẹ̀ tó péye jù lọ tí Ẹ̀ka Tó Ń Ṣèwádìí Ìwà Ìkà Táwọn Èèyàn Ń Hù Sáwọn Arúgbó Nílẹ̀ Amẹ́ríkà ní sọ pé: “Nǹkan bíi mílíọ̀nù kan sí méjì àwọn ará Amẹ́ríkà tí wọ́n jẹ́ ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ làwọn èèyàn ti pa lára, tí wọ́n ti tú jẹ, tàbí ti hùwà ìkà sí láwọn ọ̀nà mìíràn. Bẹ́ẹ̀ àwọn tí wọ́n gbára lé pé wọ́n á tọ́jú àwọn tí wọ́n á sì dáàbò bo àwọn ló ń ṣe nǹkan wọ̀nyí sí wọn.” Igbá kejì agbẹjọ́rò àgbègbè kan nílùú San Diego ní ìpínlẹ̀ California, sọ pé híhùwà ìkà sáwọn arúgbó jẹ́ “ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tó burú jù lọ táwọn agbófinró ń dojú kọ lóde òní.” Ó fi kún un pé: “Bí mo ṣe ń wo ìṣòro yìí, yóò túbọ̀ burú sí i láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí.”
• Ohun tó ń ká àwọn ara ìlú Canterbury lórílẹ̀-èdè New Zealand lára báyìí ni báwọn èèyàn ṣe ń gba tọwọ́ àwọn arúgbó, ì báà jẹ́ owó tàbí ohun ìní wọn. Àwọn ará ilé wọn, àgàgà àwọn tó jẹ́ ajoògùnyó, ọ̀mùtípara àtàwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ ló sì ń ṣe nǹkan wọ̀nyí sí wọn. Iye àwọn arúgbó tí wọ́n ń hùwà ìkà sí níbẹ̀ ti pọ̀ sí i gan-an, látorí márùnlélọ́gọ́ta [65] lọ́dún 2002 sí ọgọ́rùn-ún ó lé méje [107] lọ́dún 2003. Ọ̀gá àgbà àjọ kan tí wọ́n dá sílẹ̀ láti dáwọ́ ìwà ìkà táwọn èèyàn ń hù sáwọn arúgbó dúró sọ pé “díẹ̀ péré” ni iye tá a mẹ́nu kàn yìí wulẹ̀ jẹ́ lára iye àwọn arúgbó tó ń dojú kọ ìṣòro yìí.
• Ìwé ìròyìn The Japan Times sọ pé Ẹgbẹ́ Àwọn Agbẹjọ́rò Nílẹ̀ Japan sọ pé, “àwọn arúgbó tí wọ́n ń hùwà ìkà sí ló yẹ ká túbọ̀ fún láfiyèsí ju àwọn ọmọdé tí wọ́n ń hùwà àìdáa sí tàbí àwọn mìíràn tí wọ́n ń hùwà ìkà sí nínú ilé.” Kí nìdí? Ìwé ìròyìn Times sọ pé ìdí kan ni pé, “tá a bá fi ìṣòro híhùwà ìkà sáwọn arúgbó wé ìṣòro híhùwà àìdáa sọ́mọdé àti híhùwà ìkà sí ọkọ tàbí aya ẹni, tàwọn arúgbó ló máa ń pẹ́ kó tó hàn síta. Ó jẹ́ torí pé àwọn arúgbó máa ń rò pé àwọn làwọn jẹ̀bi tó bá jẹ́ pé ọmọ tiwọn gan-an ló ń hùwà ìkà sí wọn, àti torí pé ìjọba àtàwọn alábòójútó ìjọba ìbílẹ̀ kò tíì mọ bí wọ́n á ṣe bójú tó ìṣòro náà.”
Àpẹẹrẹ bíi mélòó yìí, tó jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé ló mú ká béèrè pé: Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń pa àwọn arúgbó púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tì, tí wọ́n sì ń hùwà ìkà sí wọn? Ǹjẹ́ ìrètí tiẹ̀ wà pé nǹkan máa yí padà lọ́jọ́ iwájú? Kí ló lè tu àwọn arúgbó nínú?