Àwọn Ọlọ́kàn Tútù Ni Yóò Jogún Ayé
“Mo fojú inú wò ó pé àyípadà máa bá àtèèyàn àtẹranko àtohun ọ̀gbìn, tí gbogbo nǹkan yóò sì padà dára. . . . Àmọ́ ọ̀la òde yìí kọ́ ló máa ṣẹlẹ̀ o, ó ṣì dẹ̀yìn wá ọ̀la, nígbà tí ọ̀run tuntun àti ayé tuntun bá dé.”—Jean-Marie Pelt, ọmọ ilẹ̀ Faransé tó jẹ́ ògbóǹkangí onímọ̀ nípa àyíká.
Ọ̀RỌ̀ ilé ayé yìí ti sú ọ̀pọ̀ èèyàn. Inú wọn ì bá sì dùn tí ayé yìí bá lè di Párádísè. Ṣùgbọ́n ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí kọ́ ló ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wu àwọn èèyàn kí ayé di Párádísè o. Ó pẹ́ tí Bíbélì ti sọ pé ayé ṣì máa padà di Párádísè. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé, “awọn ọlọ́kàntútù . . . [yóò] jogún ayé” àti “ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bii ti ọrun bẹẹ ni ni ayé,” wà lára ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó. (Mátíù 5:5; 6:10, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Àmọ́ lóde òní, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló gbà gbọ́ pé ayé ṣì máa di Párádísè táwọn ọlọ́kàn tútù yóò máa gbé. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó tiẹ̀ pe ara wọn ní Kristẹni ló gbà pé ayé ò lè padà di Párádísè mọ́ láé.
Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Faransé náà La Vie sọ ìdí táwọn èèyàn, pàápàá àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì, ò fi nígbàgbọ́ nínú Párádísè mọ́, yálà Párádísè orílẹ̀-ayé ni o tàbí ti ọ̀run. Ó ní: “Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá [1,900] ọdún ni ọ̀rọ̀ nípa Párádísè fi jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ẹ̀kọ́ tí ìjọ Kátólíìkì ń kọ́ni, àmọ́ ní báyìí irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ kì í wáyé mọ́ lásìkò ìpàgọ́ tí wọ́n ti ń fàdúrà jagun, nígbà ìsìn ọjọ́ Sunday, nígbà ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìsìn àti nínú ẹ̀kọ́ katikísìmù.” Ó wá fi kún un pé Párádísè ti wá di “àdììtú ọ̀rọ̀ tó rúni lójú gan-an.” Àwọn oníwàásù kan tiẹ̀ máa ń dìídì yẹ ọ̀rọ̀ nípa Párádísè sílẹ̀, wọ́n ló “ti máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ronú nípa ayọ̀ lórílẹ̀-ayé púpọ̀ jù.”
Onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá náà, Frédéric Lenoir, tó tún jẹ́ ògbóǹkangí nínú ọ̀rọ̀ ìsìn, gbà pé Párádísè ò jẹ́ nǹkan gidi mọ́, ó ní “àkàwé lásán ni.” Bákan náà ni òpìtàn Jean Delumeau, tó ti kọ ọ̀pọ̀ ìwé lórí Párádísè, ṣe rò pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ò ní ṣẹ gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ gan-an, pé àpèjúwe ni wọ́n kàn jẹ́. Ó sọ nínú ìwé rẹ̀ pé: “Ní ti ìbéèrè náà, ‘Kí ló kù tá a tún fẹ́ máa sọ nípa Párádísè?’ ohun kan wà tí ẹ̀kọ́ ìsìn Kristẹni jẹ́ kó yé wa, òun náà ni pé: Níwọ̀n bí Olùgbàlà ti jíǹde, ó dájú pé lọ́jọ́ kan ṣá, a ó pàdé nílé ayọ̀.”
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ǹjẹ́ ó ṣì bọ́gbọ́n mu láti máa sọ̀rọ̀ nípa Párádísè orílẹ̀-ayé? Ibo lọ̀rọ̀ ilé ayé wa yìí yóò já sí gan-an? Ǹjẹ́ a lè róye bí ọjọ́ ọ̀la yóò ṣe rí àbí a ò tiẹ̀ lè mọ nǹkan kan nípa rẹ̀ rárá? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Emma Lee/Life File/Getty Images