ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 9/15 ojú ìwé 32
  • “Mo Mà Nífẹ̀ẹ́ Òfin Rẹ O!”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Mo Mà Nífẹ̀ẹ́ Òfin Rẹ O!”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 9/15 ojú ìwé 32

“Mo Mà Nífẹ̀ẹ́ Òfin Rẹ O!”

ŃṢE lẹni tó kọ Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà [119] fi orin yẹn sọ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe rí lọ́kàn rẹ̀. Ó kọ ọ́ lórin pé: “Inú ọkàn-àyà mi ni mo fi àsọjáde rẹ ṣúra sí.” “Èmi yóò fi ìfẹ́ni hàn fún àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ.” “Ọkàn mi ni a ti bò mọ́lẹ̀ nítorí yíyánhànhàn fún àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ ní gbogbo ìgbà.” “Àwọn ìránnilétí rẹ ni mo ní ìfẹ́ni fún.” “Mo ń yánhànhàn fún àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ.” “Èmi yóò sì fi ìfẹ́ni hàn fún àwọn àṣẹ rẹ tí mo ti nífẹ̀ẹ́.” “Èmi yóò máa fi àwọn ìlànà rẹ ṣe ìdàníyàn mi.” “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”—Sáàmù 119:11, 16, 20, 24, 40, 47, 48, 97.

Onísáàmù náà mọyì ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ṣí payá fún wa gan-an ni! Ǹjẹ́ ìwọ náà mọyì ohun tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ṣé ìwọ náà yóò fẹ́ láti fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bíi ti onísáàmù yìí? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ohun tó o máa kọ́kọ́ ṣe ni pé kó o jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ka Bíbélì déédéé, àní kó o máa kà á lójoojúmọ́ tó bá ṣeé ṣe. Jésù Kristi sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mátíù 4:4) Ohun kejì ni pé o ní láti máa ṣàṣàrò lórí ohun tó o kà. Tó o bá ń ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tí Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run, nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀, àwọn ohun tó fẹ́ ká máa ṣe àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú, wàá túbọ̀ mọyì Bíbélì gan-an. (Sáàmù 143:5) Sì tún rí i dájú pé ò ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yíyèkooro tó wà nínú Bíbélì nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe.—Lúùkù 11:28; Jòhánù 13:17.

Àǹfààní wo lo máa jẹ tó o bá fẹ́ràn ọ̀rọ̀ Bíbélì? Sáàmù 119:2 sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń pa àwọn ìránnilétí [Ọlọ́run] mọ́.” Àwọn ìránnilétí inú Bíbélì á jẹ́ kó o mọ bí wàá ṣe lè máa yanjú àwọn ìṣòro tó o bá ní. (Sáàmù 1:1-3) Yóò mú kó o ní ọgbọ́n àti ìjìnlẹ̀ òye tí wàá lè fi máa ‘kó ẹsẹ̀ rẹ ní ìjánu kúrò nínú gbogbo ipa ọ̀nà búburú.’ (Sáàmù 119:98-101) Mímọ̀ tó o bá mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àtohun tó fẹ́ ṣe nípa ọ̀rọ̀ ayé yìí yóò jẹ́ kó o lè gbé ìgbé ayé tó túbọ̀ nítumọ̀, yóò sì jẹ́ kó o nírètí pé ọjọ́ ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa.—Aísáyà 45:18; Jòhánù 17:3; Ìṣípayá 21:3, 4.

Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn gan-an láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ mọ Bíbélì sí i kí wọ́n sì fẹ́ràn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀. Inú wa yóò sì dùn tó o bá gbà pé ká wá ọ wá bá a ṣe sọ nísàlẹ̀ yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́