Daniel Àti Káàdì Ìpàdé Àgbègbè Rẹ̀
JÉSÙ bá àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí wọ́n jẹ́ olódodo lójú ara wọn wí nígbà tí wọ́n ń bínú nítorí pé wọ́n rí àwọn ọmọdékùnrin tó ń yin Ọlọ́run lógo ní gbangba. Ó wá bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ kò tíì ka èyí rí pé, ‘Láti ẹnu àwọn ìkókó àti àwọn ọmọ ẹnu ọmú ni o ti mú ìyìn jáde’?”—Mátíù 21:15, 16.
Daniel tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà, tó ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Rọ́ṣíà nílẹ̀ Jámánì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọmọdé ṣì ń yin Jèhófà lógo lákòókò tiwa yìí. Òun àti ìyá rẹ̀ àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin lọ sípàdé àgbègbè táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe nílùú Duisburg. Ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa lọ sírú àpéjọ ńlá bẹ́ẹ̀ nìyẹn. Gbogbo nǹkan tí wọ́n rí níbẹ̀ ló ń yà wọ́n lẹ́nu. Lára àwọn nǹkan náà ni òtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n dé sí, báwọn èèyàn ṣe pọ̀ gan-an, jíjókòó tí wọ́n jókòó fún odindi ọjọ́ mẹ́ta láti gbọ́rọ̀, àti bí wọ́n ṣe rí àwọn tó ṣèrìbọmi, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti àwòkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n wò. Báwo ni Daniel ṣe ṣe níbẹ̀? Ìṣe rẹ̀ wúni lórí gan-an.
Gbogbo wọn wá padà wálé lẹ́yìn àpéjọ náà. Nígbà tó sì di ọjọ́ Monday tó tẹ̀ lé e, Daniel tètè jí láti múra ilé ìwé jẹ́lé-ó-sinmi tó máa ń lọ. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó tún fi sáyà? Káàdì tó fi hàn pé ó lọ sípàdé àgbègbè ni! Màmá rẹ̀ wá sọ fún un pé: “Ìpàdé àgbègbè ti parí. O lè yọ káàdì náà kúrò lára aṣọ rẹ wàyí.” Àmọ́ Daniel sọ pé: “Mo fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ ibi tí mo lọ lópin ọ̀sẹ̀ kí wọ́n sì gbọ́ nípa ohun tí mo kọ́ níbẹ̀.” Ńṣe ni Daniel fi káàdì yìí sáyà títí wọ́n fi jáde ilé ìwé lọ́jọ́ náà tó sì fi ń yangàn. Nígbà tí olùkọ́ rẹ̀ béèrè ohun tí káàdì náà wà fún, ó ṣàlàyé gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ nípàdé àgbègbè náà fún un.
Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Daniel tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọdékùnrin àtàwọn ọmọdébìnrin tí wọ́n ń fi ìyìn fún Jèhófà ní gbangba láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún títí di ìsinsìnyí.