ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 12/1 ojú ìwé 32
  • Ǹjẹ́ A Lè Tọ́ Adájọ́ Sọ́nà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ A Lè Tọ́ Adájọ́ Sọ́nà?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 12/1 ojú ìwé 32

Ǹjẹ́ A Lè Tọ́ Adájọ́ Sọ́nà?

ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ni Sladjana tó ń gbé nílẹ̀ Croatia. Lọ́jọ́ kan, wọ́n ní kó wá sílé ẹjọ́ nítorí ọ̀ràn kan tó ní í ṣe pẹ̀lú owó. Ó tètè dé, ó sì lọ bá adájọ́ kan níbẹ̀. Àmọ́, ẹni tí wọ́n jọ ní ẹjọ́ kò tètè dé. Ó wu Sladjana gan-an láti wàásù fáwọn èèyàn, nítorí náà, ó lo ìgboyà, ó lọ́ bá adájọ́ náà sọ̀rọ̀ lákòókò táwọn èèyàn ṣì ń dúró de akọ̀wé kóòtù.

Sladjana béèrè lọ́wọ́ adájọ́ náà pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé láìpẹ́ kò ní sí àwọn adájọ́ àtàwọn ilé ẹjọ́ mọ́ lórí ilẹ̀ ayé?” Àmọ́ o, ọ̀rọ̀ nípa àwọn adájọ́ òde òní ló ń sọ.

Ọ̀rọ̀ yìí ya adájọ́ náà lẹ́nu, ó wo ojú Sladjana, kò sì sọ ohunkóhun. Àkókò yẹn gan-an ni ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀. Nígbà tí wọ́n parí ẹjọ́ náà, Sladjana dìde láti fọwọ́ síwèé kan, ni adájọ́ náà bá sún mọ́ ọn, ó sì rọra béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé ohun tó o sọ yẹn dá ọ lójú, pé láìpẹ́ kò ní sí àwọn adájọ́ àtàwọn ilé ẹjọ́ mọ́ lórí ilẹ̀ ayé?”

Sladjana fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni sà, ó dá mi lójú gan-an ni!”

Adájọ́ náà wá béèrè pé: “Ṣé o lẹ́rìí tó o lè fi ti ohun tó o sọ yẹn lẹ́yìn?”

Sladjana dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ó wà nínú Bíbélì”

Adájọ́ náà sọ pé òun yóò fẹ́ rí ibi tí ẹ̀rí yẹn wà, àmọ́ kò ní Bíbélì. Nítorí náà, Sladjana sọ fún un pé òun á bá a wá Bíbélì kan. Àwọn Ẹlẹ́rìí wá lọ sọ́dọ̀ adájọ́ náà, wọ́n fún un ní Bíbélì kan, wọ́n sì gbà á níyànjú pé kó jẹ́ káwọn máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Adájọ́ yìí gbà pé kí wọ́n wá máa kọ́ òun, kò sì pẹ́ tó fi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí bá àsọtẹ́lẹ̀ inú Sáàmù 2:10 mú, èyí tó sọ pé: “Wàyí o, ẹ̀yin ọba, ẹ lo ìjìnlẹ̀ òye; ẹ gba ìtọ́sọ́nà, ẹ̀yin onídàájọ́ ilẹ̀ ayé.” Ẹ ò rí i pe ó máa ń múnú ẹni dùn gan-an nígbà tí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì jẹ́ kí Jèhófà tọ́ àwọn sọ́nà!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Sladjana àti adájọ́ náà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́