Ìgbàgbọ́ Ìyá kan Borí Ìbànújẹ́ Ọkàn
“Bẹ́ ẹ bá rí lẹ́tà yìí gbà, a jẹ́ pé mi ò ye iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ṣe fún mi nìyẹn, ẹ ò sì ní rí mi láàyè mọ́.”
ÀWỌN ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ lẹ́tà tí ìyà kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ sáwọn ọmọbìnrin rẹ̀ mẹ́ta nìyẹn. Carmen ni orúkọ obìnrin náà, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, mọ́kàndínlógún àti mẹ́rìndínlógún. Carmen ò ye iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ṣe fún un, ńṣe ló gbabẹ̀ kú.
Kéèyàn fi ọmọbìnrin mẹ́ta sílẹ̀ sínú irú ẹ̀dùn ọkàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun ìbànújẹ́ gidigidi. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ tí ìyá àwọn ọmọ yìí ní nínú Jèhófà àti nínú àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe mú un borí ìbànújẹ́ náà, èyí sì fún un ní ìbàlẹ̀ ọkàn. A rí èyí nínú lẹ́tà tó wọni lára gan-an tó kọ. Gbọ́ ohun tó sọ fáwọn ọmọbìnrin rẹ̀.
“Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mo fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi. . . . Ọmọ àtàtà lẹ jẹ́ fún mi, ọmọ àmúyangàn sì ni yín.
“Ó wù mí kí ń wà pẹ̀lú yín títí dìgbà tí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí máa fi dé . . . , ṣùgbọ́n níwọ̀n bí kò ti ṣeé ṣe báyìí, mo ti bẹ Ọlọ́run pé kó ràn yín lọ́wọ́ kẹ́ ẹ bàa lè máa jẹ́ olóòótọ́, bẹ́ ẹ ti ṣe jẹ́. A ti jọ fara da ọ̀pọ̀ àdánwò, Jèhófà ò sì fi wá sílẹ̀ nígbà kan rí. . . . Nítorí náà, ẹ máa bá a lọ láti gbára lé ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ fúnni, kẹ́ ẹ sì máa kọ́wọ́ ti ìjọ àti àwọn alàgbà lẹ́yìn. Ẹ ṣe iṣẹ́ ìwàásù débi tẹ́ ẹ bá lè ṣe é dé, kẹ́ ẹ sì nífẹ̀ẹ́ gbogbo ará.
“Ìgbà díẹ̀ la máa fi pínyà. . . . Ẹ dákun ẹ dárí jì mí fún gbogbo àṣìṣe tí mo ti ṣe, àti fún ìgbà tí mi ò gbọ́ yín yé tàbí ìgbà tí mi ò sọ fún yín bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín tó. . . . Mo mọ̀ pé ẹni kọ̀ọ̀kan yín ló nílò àwọn nǹkan kan. Jèhófà mọ ohun tẹ́ ẹ nílò ju bẹ́ ẹ ti mọ̀ ọ́n lọ, yóò sì pèsè gbogbo rẹ̀ fún yín, yòó sì san yín lẹ́san ire fún gbogbo ohun tẹ́ ẹ ti fara dà.
“Ẹ má gbàgbé ohun tẹ́ ẹ̀ ń lé o, ìyẹn ìyè nínú ayé tuntun. Ẹ máa bá a lọ láti máa sapá kọ́wọ́ yín lè tẹ̀ ẹ́. Kí Jèhófà bù kún yín, kó sì fún yín lókun kẹ́ ẹ bàa lè jẹ́ olóòótọ́ títí dé òpin. . . . Ẹ̀yin ọmọbìnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ má bọkàn jẹ́. Mo nífẹ̀ẹ́ yín!”
Nǹkan búburú lè ṣẹlẹ̀ sẹ́nikẹ́ni nígbàkigbà. Sólómọ́nì Ọba ìgbàanì kọ̀wé pé: “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” (Oníwàásù 9:11) Àwọn tí wọ́n bá ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà lè ní ìdánilójú bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó sọ pé: “Mo gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè . . . tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.”—Róòmù 8:38, 39; Hébérù 6:10.