Kò Rọrùn Láti Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
LÓDE òní, ọ̀pọ̀ èèyàn lè rò pé kò sí àǹfààní kankan nínú kéèyàn ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Àwọn tó máa ń ṣe fọ́rífọ́rí, àwọn tó máa ń gbéra ga, àtàwọn tó fẹ́ kọ́wọ́ àwọn tẹ ohun tó wù wọ́n lọ́nàkọnà, làwọn èèyàn máa ń wárí fún, àwọn ló sì dà bíi pé wọ́n rọ́wọ́ mú jù lọ. Irú ìgbésí ayé táwọn olówó àtàwọn gbajúmọ̀ ń gbé ló ń wu ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn láti máa gbé, wọn ò fẹ́ káwọn dà bí àwọn onírẹ̀lẹ̀ èèyàn àtàwọn oníwà tútù. Àwọn tó rọ́wọ́ mú sì sábà máa ń fọ́nnu pé mímọ̀ ọ́n ṣe àwọn làwọn fi débi táwọn dé. Dípò kí wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń gbéra ga tí wọ́n sì máa ń rò pé agbára àwọn làwọn fi mókè.
Olùwádìí kan nílẹ̀ Kánádà sọ pé “ẹ̀mí ‘kò-sẹ́ni-tó-gbayì-tó-mi’ ti dóde báyìí” lórílẹ̀-èdè òun. Àwọn mìíràn sì gbà pé ìgbádùn làwọn èèyàn kà sí pàtàkì ju kéèyàn jẹ́ ẹni tó mọ ohun tó tọ́, wọ́n tún ṣàkíyèsí pé tara àwọn èèyàn nìkan ni wọ́n túbọ̀ ń gbájú mọ́ lóde òní. Nínú irú ayé tó rí báyìí, kò jọ pé àwọn èèyàn á ka ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ sóhun pàtàkì.
Òótọ́ ni pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo èèyàn ni yóò sọ pé ó dára káwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ nítorí pé àwọn onírẹ̀lẹ̀ máa ń rọrùn láti bá lò. Àmọ́ nínú ayé tí ẹ̀mí ìdíje kúnnú rẹ̀ yìí, àwọn kan máa ń bẹ̀rù pé táwọn bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, òmùgọ̀ làwọn èèyàn máa ka àwọn sí.
Bíbélì tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sàsọtẹ́lẹ̀ pé lákòókò yìí, àwọn èèyàn yóò jẹ́ “ajọra-ẹni-lójú” àti “onírera.” (2 Tímótì 3:1, 2) Ǹjẹ́ o ò gbà pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń nímùúṣẹ? Ǹjẹ́ o rò pé ó dára kéèyàn ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀? Àbí o rò pé òmùgọ̀ ni wọ́n á pe ẹni tó bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ á sì rọrùn láti tàn jẹ?
Àmọ́ o, Bíbélì sọ àwọn ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká gbà pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ dára gan-an, ó sì sọ ìdí tó fi yẹ kéèyàn ní in. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì rọ̀ wá pé ká ní ànímọ́ yìí. Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kì í ṣe ìwà òmùgọ̀, pé ànímọ́ tó fi hàn pé èèyàn jẹ́ ọlọgbọ́n ni. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Kí ló yẹ kó jẹ́ èrò wa nípa àwọn àṣeyọrí tá a ṣe?