Ǹjẹ́ Gbogbo Ayé Lè Wà Níṣọ̀kan?
ǸJẸ́ ayé wa yìí máa tó dibi tó lálàáfíà àbí bèbè àjálù ńlá ló wà? Tá a bá ní ká wo ohun táwọn èèyàn ń sọ, a lè sọ pé kò sí èyí tí kò lè ṣẹlẹ̀ nínú méjèèjì yìí.
Lọ́nà kan, àwọn kan lára àwọn aṣáájú ayé ń fi gbogbo ẹnu sọ pé ayé lè di ibi tó tòrò minimini lọ́jọ́ kan. Bóyá ìdí tí wọ́n fi ń sọ bẹ́ẹ̀ ni pé tí kò bá sí àlàáfíà, ipò tí ayé máa wà á burú kọjá ohun téèyàn lè fẹnu sọ. Lọ́nà kejì, ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn kì í balẹ̀ rárá nígbà tí wọ́n bá ronú kan àwọn ìbéèrè bíi: Àwọn orílẹ̀-èdè wo ló ní àwọn ohun ìjà tó lè pa àìmọye èèyàn lẹ́ẹ̀kan náà? Ǹjẹ́ wọ́n á tiẹ̀ gbìyànjú àtilò wọ́n? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí wọ́n bá lo àwọn ohun ìjà wọ̀nyí?
Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn fi hàn pé ó pẹ́ tí ẹ̀mí ìbára-ẹni-díje àti ẹ̀tanú ti jẹ́ ìṣòro ńlá tó mú káwọn èèyàn gbà pé kò sí bí gbogbo ayé ṣe lè wà níṣọ̀kan. Ìsìn sì ti fa aáwọ̀ àti ìjà gan-an dípò tí ì bá fi paná rẹ̀. Akọ̀ròyìn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ James A. Haught kọ̀wé pé: “Ohunkóhun tó bá lè pín àwọn èèyàn níyà lè fa ìjà, ìsìn sì jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó ń pín àwọn èèyàn níyà jù lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ ni pé ìsìn máa ń mú kéèyàn jẹ́ ẹni ‘rere,’ ó hàn gbangba pé ìsìn ló tiẹ̀ ń mú káwọn èèyàn kan ṣe ohun tó burú jáì.” Irú èrò yìí náà ni òǹṣèwé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Steven Weinberg ní lọ́kàn. Ó kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ ìsìn ló ń mú káwọn èèyàn dáadáa ṣe ohun tó burú jáì.”
Ǹjẹ́ ìrètí tiẹ̀ wà pé ayé wa yìí lè wà níṣọ̀kan? Bẹ́ẹ̀ ni o! Àmọ́, kì í ṣe èèyàn tàbí àwọn ẹ̀sìn téèyàn dá sílẹ̀ ló máa mú kí ayé wà nísọ̀kan, gẹ́gẹ́ bá a ó ṣe rí i.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]
Ṣé bíi bọ́ǹbù tó fẹ́ bú gbàù layé yìí rí?