Ẹ̀kọ́ Bíbélì
ỌMỌ ỌDÚN MẸ́TA ÀTI ÀWỌN TÍ KÒ TÓ BẸ́Ẹ̀
Òjò ń rọ̀.
Táyọ̀ ń sunkún pé:
“Mi ò lè jáde.
Kí ló dé tí òjò yìí ò dá?”
Ṣùgbọ́n lójijì!
Oòrùn yọ.
Òjò sì dá.
Inú Táyọ̀ dùn!
Táyọ̀ sáré jáde, ó sì rí ohun kan tó yà á lẹ́nu.
Táyọ̀ sọ pé, “Mi ò mọ̀ pé òjò tí Ọlọ́run ń rọ̀ ni ó ń mú kí òdòdó dàgbà!”
IṢẸ́ ÒBÍ
Ní kí ọmọ rẹ tọ́ka sí:
- Fèrèsé 
- Táyọ̀ 
- Òdòdó 
- Ẹyẹ 
- Igi 
Fara balẹ̀ wá àwọn nǹkan yìí.
- Kòkòrò kan 
- Ọkọ̀ òfuurufú 
Ka Ìṣe 14:17. Kí nìdí tí Jèhófà fi dá òjò?