Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn Láti Ṣe Ara Wọn Láǹfààní
1 Jèhófà ń fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ṣe ara wọn láǹfààní. (Aísá. 48:17) Ó mọ ohun tó lè mú ojúlówó ayọ̀ wá fún wa. Ohun tó ń fẹ́ gan-an ni pé káwọn èèyàn yẹra fún àjálù ibi kí wọ́n sì máa gbádùn ìgbésí ayé nípa fífiyè sáwọn àṣẹ rẹ̀. A máa ń ṣe ara wa láǹfààní gidigidi nípa gbígbé ìgbé ayé wa lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́. (Sm. 34:8) Báwo la ṣe lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti ṣe ohun kan náà?
2 Kí Làwọn Èèyàn Ń Fẹ́? Kí ló jẹ àwọn èèyàn lógún níbi tóò ń gbé? Ǹjẹ́ kì í ṣe ààbò ilé wọn, ìdè ìgbéyàwó wọn, ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ wọn, àti àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìwọ̀nyí ni? Nígbà tí wọ́n bá níṣòro, ibo ni wọ́n máa ń yíjú sí fún ìrànwọ́? Wọ́n lè gbára lé ara wọn, wọ́n lè yíjú sí àwọn ètò ran-ra-ẹ-lọ́wọ́, wọ́n sì lè gbára lé ìmọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn. Níbi tí wọ́n ti ń ṣe èyí, ọ̀pọ̀ la ti kó ìdàrúdàpọ̀ ọkàn bá nípa àwọn èrò tí kò ṣe déédéé tí kò sì gbéṣẹ́ ní ti bí wọ́n ṣe lè ṣe ara wọn láǹfààní. A gbọ́dọ̀ mú kó dá wọn lójú pé ìtọ́sọ́nà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń pèsè ló dára jù ní gbogbo ọ̀nà. (Sm. 119:98) A lè ṣe èyí nípa fífi hàn wọ́n bí wọ́n ṣe lè mú kí ìgbésí ayé wọn sunwọ̀n sí i nísinsìnyí pàápàá bí wọ́n bá sapá láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n sì fi ohun tó sọ sílò.—2 Tím. 3:16, 17.
3 Ìgbésí Ayé Ìdílé Tí A Mú Sunwọ̀n Sí I: Díẹ̀ làwọn èèyàn tó mọ bí ìmọ̀ràn táa mí sí ní Éfésù 5:22–6:4 ṣe ń ṣiṣẹ́ dáadáa tó láti yanjú àwọn ìṣòro ìdílé. Bọ́ràn ṣe rí nìyí fún tọkọtaya kan tí wọ́n pinnu pé ṣe làwọn yóò pínyà lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí wọ́n ti ṣègbéyàwó. Ṣùgbọ́n, a bá ìyàwó rẹ̀ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a sì kọ́ ọ ní àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ nípa ìgbé ayé nínú ìgbéyàwó. Láìpẹ́, ọkọ rí i pé ìyàwó òun ti ń yí padà nítorí pé aya náà ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, lọkọ bá dara pọ̀ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ọkọ sọ lẹ́yìn náà pé: “Wàyí o, a ti rí ìpìlẹ̀ fún ìdílé aláyọ̀ tòótọ́.”
4 Ète Tòótọ́ Nínú Ìgbésí Ayé: Nígbà tí ọ̀dọ́ kan tó ti sọ oògùn lílò di bárakú wá ìrànwọ́ látọ̀dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí, a kọ́ ọ pé Jèhófà bìkítà fún un gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. Ó sọ pé: ‘Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Ẹlẹ́dàá náà ní ète kan fún èèyàn, ó sì nawọ́ ìyè àìnípẹ̀kun sáwọn tó tẹ́wọ́ gbà. Bóo bá rí bínú mi ṣe dùn tó nítorí èyí. Lónìí, mo ń gbádùn ìlera tó jíire, àlàáfíà ọkàn, àti ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.’
5 Kò sẹ́ni tí kò lè jàǹfààní láti inú ìrànwọ́ gbígbéṣẹ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nípa lílò ó gẹ́gẹ́ bí atọ́nà wa, a ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀nà Jèhófà dára fíìfíì ju àwọn ọ̀nà ayé lọ. (Sm. 116:12) Àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti mú ìhìn iṣẹ́ yìí dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, ká kọ́ wọn láti ṣe ara wọn láǹfààní. Bí a ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò rí ọ̀pọ̀ àbájáde rere.