Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù December: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ìjọ bá ní, tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1986 fún ọrẹ ₦40. Àwọn ìjọ tí kò bá ní irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ lè fi ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọni. February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A óò sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
◼ Bí ìjọ yín yóò bá yí àwọn àkókò tí ẹ ń ṣe ìpàdé padà lọ́dún tuntun, a rọ gbogbo yín láti máa lọ sí ìpàdé déédéé ní àwọn àkókò tuntun náà. Ẹ sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn olùfìfẹ́hàn yòókù nípa ìyípadà èyíkéyìí tó bá ṣẹlẹ̀, ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí lo àwọn ìwé ìléwọ́ tó ń fi ìṣètò tuntun náà hàn.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní December 1 tàbí bí ó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ fi tó ìjọ létí lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó tó tẹ̀ lé e.