Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, ọrẹ àtinúwá nìkan la ó gbà. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A ó sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé. April àti May: Àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ́wọ́ nítorí àwọn èèyàn tó bá fìfẹ́ hàn, kí o sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé. ÀKÍYÈSÍ: Kí àwọn ìjọ tó bá fẹ́ àwọn ìwé táa mẹ́nu kàn lókè yìí, tí a ó lò nínú iṣẹ́ ìsìn pápá béèrè fún un nínú Literature Request Form (S-14).
◼ Kí akọ̀wé àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò gbogbo aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bó bá ṣòro fún ẹnikẹ́ni lára wọn láti ní iye wákàtí tí a ń béèrè, kí àwọn alàgbà ṣètò láti ràn án lọ́wọ́. Fún ìdámọ̀ràn, ẹ ṣàtúnyẹ̀wò àwọn lẹ́tà ọlọ́dọọdún náà, S-201 ti October 1, tí Society kọ. Ẹ tún wo ìpínrọ̀ 12 sí 20 nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1986.
◼ A ó ṣètò àyè ìjókòó lọ́tọ̀ fáwọn adití níbi àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe tí a to orúkọ wọn sísàlẹ̀ yìí, níbi tí a ó ti túmọ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ sí èdè àwọn adití: Akabo (EE-8): May 6, 7 àti August 27; Badagry (WE-19): April 9 àti September 2, 3; Igwuruta Ali (EE-22): April 1 àti August 5, 6; Iléṣà (WE-15): May 21 àti October 7, 8; Kàdúná (NE-1B): April 8, 9 àti July 22; Ọ̀tà (WE-20): May 13, 14 àti August 20; Ùbogò (ME-19): February 5, 6 àti June 25.