Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A ó sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn nínú ilé wọn. April àti May: Àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ́wọ́ nítorí àwọn èèyàn tó bá f ìfẹ́ hàn, kí o sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn nínú ilé wọn. June: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Pọkàn pọ̀ sórí bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn nínú ilé wọn.
◼ Kí àwọn akéde tí wọ́n fẹ́ láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù April àti May wéwèé nísinsìnyí, kí wọ́n sì tètè forúkọ sílẹ̀. Èyí á ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti ṣè àwọn ètò tó yẹ fún iṣẹ́ ìsìn pápá, kí wọ́n sì ní àwọn ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tó pọ̀ tó lọ́wọ́. Kí a máa kéde orúkọ gbogbo àwọn táa fọwọ́ sí láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún ìjọ lóṣooṣù.
◼ Ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí ní gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! O lè ṣe ẹ̀dà rẹ̀, kí o sì fi í sínú ìwé tìrẹ kí o lè máa tètè rí i lò.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní March 1, tàbí bó bá ṣe lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó tó tẹ̀ lé e.
◼ A ó ṣe Ìṣe Ìrántí ní Wednesday, April 19, 2000. Bó bá jẹ́ pé ìjọ yín máa ń ṣe ìpàdé lọ́jọ́ Wednesday, ẹ yí ìpàdé náà sí ọjọ́ mìíràn láàárín ọ̀sẹ̀ náà bí àyè bá wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí èyí kò bá ṣeé ṣe, tó sì kan Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn yín, ẹ lè fi àwọn apá tó bá kan ìjọ yín gbọ̀ngbọ̀n kún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn mìíràn.
◼ Kí àwọn tí ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ fi gbogbo ìforúkọsílẹ̀ fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ránṣẹ́ nípasẹ̀ ìjọ, yálà ìforúkọsílẹ̀ tuntun tàbí èyí tó fẹ́ parí ṣùgbọ́n tí wọ́n fẹ́ kó máa bá a nìṣó.
◼ Kì í ṣe Society ló ń kọ ìwé ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alábòójútó olùṣalága ṣètò fún ìfilọ̀ lóṣooṣù kí a tó fi ìbéèrè olóṣooṣù fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sí Society kí gbogbo ẹni tó bá fẹ́ gba ìwé ti ara rẹ̀ lè sọ fún arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi àwọn ìtẹ̀jáde tó jẹ́ ìbéèrè àkànṣe sọ́kàn.