ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/00 ojú ìwé 2-7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 8/00 ojú ìwé 2-7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù August: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n tó tẹ̀ lé e yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye—Báwo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae àti Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? Ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, ni a lè fi lọni níbi tó bá yẹ. September: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. October: Àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Bí wọ́n bá fi ìfẹ́ hàn nígbà ìpadàbẹ̀wò, a lè fi ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn lọni. Bẹ̀rẹ̀ láti apá ìparí oṣù yìí, a óò pín Ìròyìn Ìjọba, nọnba 36 kiri, èyí tó ní àkọlé náà, “Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun—Kí Ni Ká Máa Retí.” November: Pípín Ìròyìn Ìjọba, nọnba 36 kiri yóò máa bá a nìṣó. Àwọn ìjọ tó bá kárí ìpínlẹ̀ wọn tán nípa mímú Ìròyìn Ìjọba, nọnba 36 dé ọ̀dọ̀ gbogbo onílé àti ibi tí àwọn ènìyàn wà, lè fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀ lọni. Bí àwọn èèyàn bá ti ní ìwọ̀nyí tẹ́lẹ̀, a lè lo ìwé Walaaye Titilae.

◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní September 1, tàbí bó bá ṣe lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó tó tẹ̀ lé e.

◼ A ń kó àwọn fọ́ọ̀mù tí ó tó láti lò ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2001 ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fọgbọ́n lo àwọn fọ́ọ̀mù wọ̀nyí. Ète tí a torí rẹ̀ ṣe wọ́n nìkan ni kí ẹ lò wọ́n fún.

◼ Ní August 31, 2000 tàbí kó ṣáà má jìnnà sí ọjọ́ yẹn rárá, kí ẹ ṣírò gbogbo iye ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ bí a ti ń ṣe lọ́dọọdún. Ìṣirò yìí jọ bí ẹni tó ń ṣe kòkáárí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ṣe máa ń kà á ní ti gidi lóṣooṣù, kí ẹ sì kọ àròpọ̀ wọn sórí fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18). Àròpọ̀ iye ìwé ìròyìn tí ó wà lọ́wọ́ ni ẹ lè mọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé ìròyìn ní ìjọ kọ̀ọ̀kan nínú àwọn tí ẹ jọ ń gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ pọ̀. Olúkúlùkù ìjọ tí ń ṣe kòkáárí yóò gba fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18) mẹ́ta. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ẹ̀dà àkọ́kọ́ ránṣẹ́ sí Society, ó pẹ́ tán ní September 6. Ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì yín. Ẹ lè lo ẹ̀dà kẹta gẹ́gẹ́ bí èyí tí ẹ óò kọ nǹkan sí. Kí akọ̀wé ìjọ tí ń ṣe kòkáárí bójú tó ìṣirò náà. Akọ̀wé àti alábòójútó olùṣalága ìjọ tí ń ṣe kòkáárí ni kó fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà.

◼ Bẹ̀rẹ̀ ní August 20, 2000, títí di September 2, 2000, Society yóò ṣírò gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà lọ́wọ́ ní Bẹ́tẹ́lì Igieduma. Nítorí ìṣirò tí a fẹ́ ṣe yìí, a kò ní ṣiṣẹ́ lórí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ béèrè pé kí a fi ránṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní lè rí wọn kó ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí.

◼ Inú wa dùn láti sọ fún yín pé, ní báyìí, ilé ìgbàwé ní Igieduma ti wà ní ṣíṣí fún gbogbo ènìyàn. Èyí túmọ̀ sí pé nígbàkigbà tí ẹ bá ṣèbẹ̀wò sí iléeṣẹ́ ẹ̀ka, yóò ṣeé ṣe láti gba ìwé ìròyìn àti àwọn ìtẹ̀jáde díẹ̀. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kíyè sí i pé ẹ kò ní lè rí àwọn èyí tí a máa ń béèrè ní àkànṣe gbà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n o, a rọ̀ yín pé kí ẹ gbìyànjú gidigidi láti máa gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yín nípasẹ̀ ìjọ, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ọ̀nà yẹn ni Society máa ń lò láti fún àwọn ìjọ ni ohun tí wọ́n bá nílò.

◼ A ti ṣe àwọn àyípadà tó wà nísàlẹ̀ yìí nínú “Àwọn Ibi Tí A Ó Ti Ṣe Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ti Ọdún 2000” tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 2000. Kí alábòójútó olùṣalága ìjọ èyíkéyìí tí a bá ti yí àkókò tàbí ibi tí wọn yóò ti ṣe àpéjọpọ̀ padà jọ̀wọ́ ṣètò kí a ṣèfilọ̀ rẹ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí wọn yóò ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá ti rí ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí gbà.

October 27-29, 2000

SÚLÈJA 1 (Yorùbá) Y-13B

ÙLÌ 1 (Ìgbò) IB-6: Akoh, Iyiukwu, Mmakwum, Okpuno Okwu, Omabala, àti Ububa; IB-7, 33

NOVEMBER 3-5, 2000

SÚLÈJA 2 (Gẹ̀ẹ́sì) NE-1B: P sí Z; NE-7.

NOVEMBER 10-12, 2000

AGBOR 2 (Gẹ̀ẹ́sì) ME-10: Oloa; ME-11; ME-13: A sí I

JOS 3 (Gẹ̀ẹ́sì) NE-3: Àwọn ìjọ tí a kò yàn sí Jos 2; NE-4.

ZARIA (Gẹ̀ẹ́sì) NE-1A, NE-2.

NOVEMBER 17-19, 2000

SÚLÈJA 3 (Gẹ̀ẹ́sì, Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà) NE-1B: A sí O; NE-5.

NOVEMBER 24-26, 2000

ÙLÌ 5 (Gẹ̀ẹ́sì) EE-9: A sí J; EE-10; EE-24: Agba, Central (Onitsha), Enugu Agidi, Express, Ezinato, GRA, Nimo, Trans-Nkisi, Umudike, Umunachi, àti Umuokwara

DECEMBER 1-3, 2000

ÙLÌ 6 (Ìgbò) IB-29; IB-22: A sí O; IB-25.

DECEMBER 8-10, 2000

AGBOR 6 (Gẹ̀ẹ́sì) ME-10: Enede; ME-15: A sí N; ME-17; ME-18: Emu Uno

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́