ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/01 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 4/01 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Níbi tí wọ́n bá ti fi ìfẹ́ hàn nígbà ìpadàbẹ̀wò, a lè fi ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn lọni. Fi ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, kí o ní in lọ́kàn pé o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. June: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Gbájú mọ́ bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. July: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n tó tẹ̀ lé e yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Báwo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” Àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, àti Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! ni a lè fi lọni tó bá yẹ.

◼ Ó pọndandan pé kí Society máa ní àkọsílẹ̀ tó bágbà mu nípa àdírẹ́sì àti tẹlifóònù gbogbo alábòójútó olùṣalága àti akọ̀wé. Bí ìyípadà èyíkéyìí bá wà nígbàkigbà, kí akọ̀wé kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù Presiding Overseer/Secretary Change of Address (S-29) kí ó sì fi í ránṣẹ́ sí Society lọ́gán.

◼ Kí àwọn akọ̀wé ìjọ máa rí i pé ìjọ ní àwọn fọ́ọ̀mù ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn Application for Regular Pioneer Service (S-205) àti Application for Auxiliary Pioneer Service (S-205b) tí ó tó lọ́wọ́. Ẹ lè béèrè fún wọn lórí Literature Request Form (S-14). Kí ẹ rí i pé ó kéré tán, èyí tó wà lọ́wọ́ yóò tó ìjọ lò lọ́dún kan. Ẹ máa ṣàyẹ̀wò gbogbo fọ́ọ̀mù ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé láti rí i dájú pé wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sínú wọn dáadáa. Bí àwọn tó fẹ́ di aṣáájú ọ̀nà kò bá lè rántí déètì náà gan-an tí wọ́n ṣe ìrìbọmi, kí wọ́n fojú díwọ̀n déètì kan kí wọ́n sì kọ ọ́ pa mọ́.

◼ A fẹ́ ṣe ìyípadà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a ṣe fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ July 30, 2001, a óò bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà, Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní, ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.

◼ Kí àwọn tó ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ fi gbogbo ìforúkọsílẹ̀ fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí wọ́n rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn ránṣẹ́ nípasẹ̀ ìjọ, yálà ìforúkọsílẹ̀ tuntun tàbí èyí tó fẹ́ parí ṣùgbọ́n tí wọ́n fẹ́ kó máa bá a nìṣó.

◼ Kì í ṣe Society ló ń kọ ìwé ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alábòójútó olùṣalága ṣètò fún ìfilọ̀ lóṣooṣù kí á tó fi ìbéèrè olóṣooṣù fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sí Society kí gbogbo ẹni tó bá fẹ́ gba ìwé ti ara rẹ̀ lè sọ fún arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi àwọn ìtẹ̀jáde tó jẹ́ ìbéèrè àkànṣe sọ́kàn.

◼ Ní May 26, 2001, a óò ti ilé Bẹ́tẹ́lì. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe wá ṣèbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe wá fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ náà.

◼ Nígbàkigbà tí o bá fúnra rẹ wéwèé láti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, tí o sì máa lọ sí ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọpọ̀ àgbègbè níbẹ̀, ọ̀dọ̀ ọ́fíìsì ẹ̀ka tó ń bójú tó iṣẹ́ wa ní orílẹ̀-èdè yẹn ni kí o ti béèrè ìsọfúnni nípa déètì, àkókò, àti ibi tí wọ́n á ti ṣe é. Àdírẹ́sì àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka wà ní ojú ewé tó kẹ́yìn nínú ìwé Yearbook wa ti lọ́ọ́lọ́ọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́