Mímọrírì Ohun Tá A Ní
1 Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ipò wa ṣe yàtọ̀ sí ti ayé pé oúnjẹ tẹ̀mí púpọ̀ rẹpẹtẹ yóò wà fún àwọn èèyàn Ọlọ́run ní àkókò òpin yìí. Ọlọ́run wí pé: “Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò jẹun, ṣùgbọ́n ebi yóò pa ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò mu, ṣùgbọ́n òùngbẹ yóò gbẹ ẹ̀yin.” Jèhófà ti mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ láásìkí gidigidi nípa pípèsè ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí fún wọn. Ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà bọ́ wa nípa tẹ̀mí?
2 Jésù ṣèlérí nípa ọjọ́ wa pé, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” yóò máa pín oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu fún àwọn tí ohun tí wọ́n ṣaláìní nípa tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn. (Mát. 5:3; 24:45-47) Ẹgbẹ́ ẹrú náà ti fi ìṣòtítọ́ ṣe èyí.
3 Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà pàtàkì tí wọ́n fi ń bọ́ wa nípa ti ẹ̀mí. A tún ní ìwé ìròyìn Jí! àti àwọn ìwé pẹlẹbẹ, ìwé kékeré àti àwọn ìwé ńlá lónírúurú fún dídá wa lẹ́kọ̀ọ́. Ǹjẹ́ o mọrírì àwọn ìpèsè tẹ̀mí wọ̀nyí? Ó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀.—Héb. 12:16.
4 A ti kíyè sí i pé àwọn ìwé ẹlẹ́yìn rírọ̀ kò lágbára tó àwọn ìwé ẹlẹ́yìn líle, wọ́n sì tètè máa ń gbó. Ọ̀nà kan tí a lè gbà fi ìmọrírì wa hàn fún ohun tí a ní ni bíbìkítà nípa bí a ṣe ń lo àwọn ìwé wọ̀nyẹn. Mímọ̀ pé àwọn ohun ìní tí a yà sí mímọ́ la ń lò yóò mú kí olúkúlùkù wa fiyè gidigidi sí ọ̀ràn yìí. Kí àwọn òbí sapá láti kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n máa bìkítà nípa bí wọ́n ṣe ń lo àwọn ìwé wa, kí àwọn òbí fúnra wọn sì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú èyí. Bí a bá túbọ̀ ń bìkítà nípa bí a ṣe ń lo àwọn ìwé wa, a ò ní máa pààrọ̀ wọn lóòrèkóòrè. Èyí á wá dín ìnáwó Society kù kí wọ́n lè fi owó tí a ti yà sí mímọ́ ṣe ohun púpọ̀ sí i.—Jòh. 6:12.
5 Ní tòótọ́, a ti bù kún wá. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a nìṣó láti fi ìmọrírì hàn fún ohun tá a ní nípa ṣíṣìkẹ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè.—Kól. 3:15, 17.