ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/04 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 3/04 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A ó sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Bí àwọn onílé bá ti ní ìwé yìí, a lè fi ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! lọ̀ wọ́n. April àti May: Kí a fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni. Nígbà tá a bá padà lọ bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò, bóyá tá a lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí tàbí àwọn ìpàdé mìíràn tí ìjọ ṣètò rẹ̀ àmọ́ tí wọn kò dara pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú ètò àjọ Ọlọ́run, kí a fún wọn ní ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run. Kí a sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, pàápàá pẹ̀lú àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tẹ́lẹ̀. June: Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Bí àwọn onílé bá sọ pé àwọn ò lọ́mọ, fún wọn ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Nígbà tó o bá ń lo ìwé pẹlẹbẹ náà, sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

◼ Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa níbí kì í fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sí akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alábòójútó olùṣalága ṣètò kí a máa ṣèfilọ̀ lóṣooṣù kí a tó fi fọ́ọ̀mù tí a fi ń béèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ nílò fún oṣù kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, kí olúkúlùkù ẹni tó bá fẹ́ láti gba ìwé tó nílò lè sọ fún arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rántí pé àwọn ìtẹ̀jáde kan wà tá a máa ń béèrè fún lọ́nà àkànṣe o.

◼ Kí akọ̀wé ìjọ rí i pé òun ń fún Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ní ìsọfúnni tó bágbà mu nípa gbogbo àwọn akéde tó ti ṣèrìbọmi tí wọ́n ti fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù Kingdom Hall Volunteer Worker Questionnaire (S-82). Nígbà tí ipò olùyọ̀ǹda ara ẹni kan bá yí padà, irú bíi nígbà tó bá ṣí lọ síbòmíràn, tàbí tí a bá yàn án gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà, kí a kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù tuntun lọ́gán, kí akọ̀wé ìjọ sì fi í ránṣẹ́. Bí àdírẹ́sì tàbí nọ́ńbà tẹlifóònù olùyọ̀ǹda ara ẹni kan bá yí padà, tàbí tí kò bá ṣe dáadáa nínú ìjọ mọ́, kí àwọn alàgbà kọ lẹ́tà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti fi èyí tó Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn létí. Kí a máa kó àwọn fọ́ọ̀mù S-82 tí a ti fọwọ́ sí tó wà nínú fáìlì ìjọ fún alábòójútó àyíká nígbà tó bá ń bẹ ìjọ wò kó lè ṣàyẹ̀wò wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́