Lẹ́tà Láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì
Ẹ̀yin Akéde Ìjọba Ọ̀wọ́n:
Ohun ìwúrí kan ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí nípa iṣẹ́ títẹ ìwé ìròyìn wa ní Nàìjíríà. Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti fọwọ́ sí i pé ká ní ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ńlá kan fún iṣẹ́ ìwé títẹ̀ wa. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé mẹ́rin tá a ní lè tẹ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] ìwé ìròyìn ní wákàtí kan, àmọ́ ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ńlá yìí lè tẹ ẹgbàá mọ́kàndínlógún [38,000] ìwé ìròyìn ní wákàtí kan. Èyí túmọ̀ sí pé a ti ń gbára dì láti máa tẹ ìwé púpọ̀ sí i lọ́jọ́ iwájú. Oṣù April ọdún yìí ni ẹ̀rọ ìtẹ̀wé náà dé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Igieduma, a sì ti báṣẹ́ jìnnà lórí títò ó. A nírètí pé tó bá fi máa di October 1, 2004, a ó ti bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀rọ yìí tẹ̀wé. Nípa báyìí, à ń wọ̀nà fún ìgbà tí a óò máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò fún ẹ̀yin akéde àtàwọn tó ń tẹ́tí sí wa tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní Nàìjíríà.
A ti bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ tuntun fáwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Igieduma. Àwọn ogún akẹ́kọ̀ọ́ tó wà nínú kíláàsì àkọ́kọ́ forúkọ sílẹ̀ ní July 2004 fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́sẹ̀ mẹ́jọ náà. Àwọn alábòójútó àyíká àti alábòójútó àgbègbè káàkiri Nàìjíríà ló wà nínú kíláàsì yìí. Gbogbo ohun tó jẹ mọ́ iṣẹ́ wọn látòkèdélẹ̀ la bójú tó, èyí á sì ṣe ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà nínú ìjọ àti àyíká tí wọ́n ti ń sìn láǹfààní gan-an.
À ń fojú sọ́nà, bẹ́yin náà ṣe ń fojú sọ́nà, láti “ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa” bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn 2005 yìí.—1 Kọ́r. 15:58.
Àwa arákùnrin yín,
Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Nàìjíríà