ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/04 ojú ìwé 7
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 12/04 ojú ìwé 7

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní December 27, 2004. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ November 1 sí December 27, 2004. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ

1. Kí ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó dára jù lọ láti mú kí àwọn tó ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ wa nífẹ̀ẹ́ sí kókó tí à ń sọ̀rọ̀ lé? [be-YR ojú ìwé 218 ìpínrọ̀ 3]

2. Sọ àwọn ohun márùn-ún tó lè mú kí ìparí ọ̀rọ̀ kan jẹ́ èyí tó múná dóko. [be-YR ojú ìwé 220 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 221 ìpínrọ̀ 4]

3. Báwo la ṣe lè rí i dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ wa jóòótọ́ délẹ̀? [be-YR ojú ìwé 224 àpótí]

4. Báwo la ṣe lè rí i dájú pé bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ tá a ní láwọn ìpàdé ń fi hàn pé a fọwọ́ pàtàkì mú jíjẹ́ tí ìjọ jẹ́ “ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́”? (1 Tím. 3:15) [be-YR ojú ìwé 224 ìpínrọ̀ 1 sí 4]

5. Nígbà tá a bá fẹ́ mẹ́nu kan àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́, tàbí a fẹ́ fa ìsọfúnni yọ látinú ibì kan tàbí a fẹ́ sọ àwọn ìrírí, báwo la ṣe lè fi Òwe 14:15 sílò? [be-YR ojú ìwé 225 ìpínrọ̀ 1]

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ

6. “Ayé” wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nínú Éfésù 1:4? [w02-YR 6/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 4]

7. Ọ̀nà mẹ́ta wo ni Sátánì ń gbà ṣáá láti rí i pé òun ba ìṣòtítọ́ wa jẹ́, ìdí wo ló sì fi jẹ́ pé àwọn ìmọ̀ràn tí ń ṣini lọ́nà àtàwọn ọ̀rọ̀ tó kù díẹ̀ káàtó látẹnu àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa ló ń lò jù? [w02-YR 8/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1; ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 4]

8. Ìlànà wo la lè rí kọ́ nínú 1 Kọ́ríńtì 6:7? [w02-YR 11/1 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 2]

9. Nígbà tá a bá ń ‘wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin wa,’ kí ló máa fi hàn pé a tọrọ àforíjì látọkànwá? (Mát. 5:23, 24) [w02-YR 11/1 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 1 àti 5]

10. Ẹ̀kọ́ wo ni 2 Ọba 13:18, 19 kọ́ wa nípa bó ṣe yẹ ká ṣe àwọn iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wa? [w02-YR 12/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1 àti 2]

BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀

11. Kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi lè fún àtìpó tàbí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ní ẹran tí wọn ò dúńbú tàbí kí wọ́n tà á fún wọn nígbà tó jẹ́ pé àwọn fúnra wọn ò lè jẹ ẹ́? (Diu. 14:21)

12. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú Diutarónómì 20:5-7?

13. Kí nìdí tí Bíbélì ṣe fi fífi ipá gba “ọlọ ọlọ́wọ́ tàbí ọmọ orí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò” wé fífi ipá gba “ọkàn”? (Diu. 24:6)

14. Níwọ̀n bí a ti ka jíjẹ ọ̀rá léèwọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí ni jíjẹ tí wọ́n jẹ “ọ̀rá àwọn àgbò” túmọ̀ sí? (Diu. 32:13, 14)

15. Ohun wo ló ń ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ òní tó bá ìwà ẹ̀ṣẹ̀ tí Ákáánì hù dọ́gba? (Jóṣ. 7:1-26) [w86-YR 12/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 20]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́