Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù: January: Ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! tàbí ìwé pẹlẹbẹ Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi? February: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà la ó fi lọni. Bí kò bá sí, a lè lo ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!, Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀! àti Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.
◼ Ní ẹ̀ka ọ́fíìsì, à ń fẹ́ ẹni tó bá lè ṣètumọ̀ sí èdè Isoko. Ẹni náà lè jẹ́ arákùnrin tàbí arábìnrin, ó sì ti gbọ́dọ̀ ka ìwé mẹ́wàá ó kéré tán. Ó gbọ́dọ̀ gba àmì credit nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì nínú ìdánwò GCE (ordinary level) tàbí ìdánwò oníwèé mẹ́wàá WASC/SSCE. Bákan náà, kí ó gba àmì credit nínú èdè Isoko, bí ó bá ṣe é nínú ìdánwò GCE (ordinary level) tàbí WASC/SSCE (àmọ́ o àmì credit nínú èdè Isoko kò pọn dandan). Kí ẹni tó bá rò pé òun lè kúnjú ìwọ̀n tó sì fẹ́ láti sìn ní Bẹ́télì kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Kí ó kọ ìwọ̀n ìwé tó kà sínú lẹ́tà náà kó sì fi ẹ̀dà èsì ìdánwò tàbí ìwé ẹ̀rí rẹ̀ náà sínú rẹ̀. Àwọn àpọ́n tàbí àwọn tọkọtaya tí kò tíì lọ́mọ là ń fẹ́, kí wọ́n sì jẹ́ ẹni tó lè yọ̀ǹda ara wọn láti wá sí Bẹ́tẹ́lì tá a bá pè wọ́n.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù February, tàbí ó pẹ́ tán láti March 6, àsọyé fún gbogbo èèyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni “Ẹ Máa Hùwà Ọlọ́gbọ́n Nínú Ayé Aláìlọ́gbọ́n Yìí.”
◼ Kí àwọn ìjọ ṣètò tó yẹ láti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí lọ́dún yìí ní ọjọ́ Thursday, March 24, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àsọyé náà lè bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, gbígbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí kiri kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ àyàfi lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Ẹ wádìí ládùúgbò láti mọ ìgbà tí oòrùn máa ń wọ̀ lágbègbè yín. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ti dára ni pé kí ìjọ kọ̀ọ̀kan dá ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí tiwọn, kì í ṣeé ṣe nígbà mìíràn. Tó bá jẹ́ pé àwọn ìjọ mélòó kan ni wọ́n jọ ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lè lọ gba ibòmíràn tí wọn yóò lò lálẹ́ ọjọ́ yẹn. A dábàá pé níbi tó bá ti ṣeé ṣe, kí ó tó ogójì ìṣẹ́jú ó kéré tán, lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ìjọ kan kí ti ìjọ tó tẹ̀ lé e tó bẹ̀rẹ̀ kí olúkúlùkù lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ayẹyẹ náà. Ó yẹ kí a tún ronú nípa bí àwọn ọkọ̀ tá a óò gbé wá kò ṣe ní ṣèdíwọ́ àti nípa ibi tí a óò gbé wọn sí, títí kan jíjá èrò sílẹ̀ àti gbígbé èrò. Kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà pinnu ètò tí yóò dára jù lọ fún ìjọ wọn.
◼ Nítorí bí Ìṣe Ìrántí ti ṣe pàtàkì tó, bí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà bá fẹ́ yan ẹni tí yóò sọ àsọyé Ìṣe Ìrántí, kí wọ́n yan ọ̀kan lára àwọn alàgbà tó tóótun jù lọ dípò kí wọ́n máa tò ó láàárín ara wọn tàbí dípò kí wọ́n máa lo arákùnrin kan náà ní gbogbo ọdún. Bí alàgbà kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró bá wà tó lè sọ àsọyé náà, òun ni kí wọ́n yàn kó sọ ọ́.
◼ A óò sọ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn lásìkò Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2005 ní Sunday, April 10. A óò ṣèfilọ̀ àkòrí àsọyé náà nígbà tó bá yá. Kí àwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àkànṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé yìí ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àkànṣe àsọyé yìí ṣáájú Sunday, April 10, 2005.
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà:
Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Grikí ní Itumọ̀ Ayé Titun—Ẹ́fíìkì
Watch Tower Publications Index—2003—Gẹ̀ẹ́sì