Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nígbà àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní October 31, 2005. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tó dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ September 5 sí October 31, 2005. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti sọ ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Kí la lè ṣe láti rí i pé ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá à ń kọ́ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n lọ́kàn? (Mát. 13:19) [be-YR ojú ìwé 258 ìpínrọ̀ 1 sí 2 àti àpótí]
2. Báwo la ṣe lè mú káwọn èèyàn máa sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde, síbẹ̀ kí la gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún? [be-YR ojú ìwé 259 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa tẹnu mọ́ àwọn àgbàyanu ànímọ́ Jèhófà fáwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́? [be-YR ojú ìwé 260, ìpínrọ̀ 1]
4. Ọ̀nà wo la lè gbà ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti mọ àwọn àtúnṣe tó yẹ kí wọ́n ṣe? [be-YR ojú ìwé 260 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 261, ìpínrọ̀ 1]
5. Kí la lè ṣe tá a fi lè ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí àwọn tó ń tẹ́tí gbọ́rọ̀ wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣàyẹ̀wò ohun tó ń sún wọn ṣe àwọn nǹkan? [be-YR ojú ìwé 262, ìpínrọ̀ 2 àti 3]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Kí ló túmọ̀ sí láti “fi taratara wá” Jèhófà, báwo la sì ṣe lè fi hàn pé à ń ṣe bẹ́ẹ̀? (Héb. 11:6) [w03-YR 8/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2; ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1 sí 2; ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 2]
7. Kí ni “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera,” báwo làwọn alàgbà sì ṣe lè fi hàn pé òun làwọn dì mú? (2 Tím. 1:13, 14) [w03-YR 1/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 1]
8. Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi pa tọkọtaya àkọ́kọ́ àti ẹ̀dá ẹ̀mí náà tó dáná ọ̀tẹ̀, ìyẹn Sátánì, run lójú ẹsẹ̀? [w03-YR 1/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 3]
9. Ojú wo ló tọ́ kéèyàn máa fi wo iṣẹ́ àti pé ǹjẹ́ ìyẹn ní kéèyàn máa ṣọ̀lẹ? (Òwe 20:4) [w03-YR 2/1 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 1]
10. Ṣé gbogbo ìgbà ló tọ̀nà pé kéèyàn fara mọ́ ẹ̀sìn àwọn òbí ẹni? [w03-YR 4/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 3]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Ǹjẹ́ 2 Ọba 13:21 fọwọ́ sí i pé ká máa júbà egungun àwọn òkú?
12. Ṣé lóòótọ́ ni Hesekáyà bá Íjíbítì ṣàdéhùn? (2 Ọba 18:19-21, 25)
13. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé ìtàn àwọn ará Ásíríà ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ọ̀nà àrà tí Jèhófà gbà ṣẹ́gun Senakéríbù, èwo ló gbádùn mọ́ ẹ jù lára àwọn àkọsílẹ̀ yẹn? (2 Ọba 19:35, 36)
14. Ta ni baba Ṣéálítíẹ́lì? (1 Kíró. 3:16-18)
15. Láwọn ọjọ́ Sọ́ọ̀lù Ọba, báwo làwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ṣe fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní? (1 Kíró. 5:18-22)