Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Àwọn ìwé tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni Iwe Itan Bibeli Mi, tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tá a tẹ̀ sórí bébà pípọ́n ràkọ̀ràkọ̀ tàbí èyí tó máa ń pàwọ̀ dà, tí ìjọ bá ní lọ́wọ́, ni kẹ́ ẹ lò. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni Mankind’s Search for God, tàbí ìwé pélébé Ẹ Máa Ṣọ́nà! February: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà ni kẹ́ ẹ lò. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀! tàbí ìwé ọlọ́jọ́ pípẹ́ míì tí èyí tí ìjọ ní lọ́wọ́ pọ̀ jù.
◼ Ẹ jọ̀wọ́, a fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé Ìṣe Ìrántí ọdún 2007 yóò jẹ́ ní ọjọ́ Monday, April 2, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. À ń fi èyí tó yín létí lásìkò kẹ́ ẹ lè tètè ṣe àwọn ètò tó yẹ tàbí kẹ́ ẹ lè wá gbọ̀ngàn tẹ́ ẹ máa lò àtàwọn ohun èèlò mìíràn bó bá jẹ́ pé ìjọ tiyín nìkan kọ́ ló ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bó bá wá jẹ́ pé ìjọ tiyín nìkan kọ́ ló ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà rí i pé àwọn ṣètò tó fìdí múlẹ̀ pẹ̀lú àwọn alákòóso gbọ̀ngàn náà láti rí i pé àwọn ìgbòkègbodò mìíràn tí wọ́n bá ṣètò sí sàkáání gbọ̀ngàn náà lọ́jọ́ yẹn kò ní dí àlàáfíà àti ìwàlétòlétò Ìṣe Ìrántí lọ́wọ́.
◼ Nítorí bí Ìṣe Ìrántí ti ṣe pàtàkì tó, bí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà bá fẹ́ yan ẹni tí yóò sọ àsọyé Ìṣe Ìrántí, kí wọ́n yan ọ̀kan lára àwọn alàgbà tó tóótun jù lọ dípò kí wọ́n máa tò ó láàárín ara wọn tàbí dípò kí wọ́n máa lo arákùnrin kan náà ní gbogbo ọdún. Bí alàgbà kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró bá wà tó lè sọ àsọyé náà, òun ni kí wọ́n yàn kó sọ ọ́.
◼ Ẹ jọ̀wọ́ ṣàtúnṣe ìpínrọ̀ 3 nínú ìtọ́ni tó wà fún Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2006 tó wà lójú ìwé 3 nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 2005, kó wá kà báyìí pé: “Kí ilé ẹ̀kọ́ yìí máa bẹ̀rẹ̀ LÁKÒÓKÒ pẹ̀lú orin, àdúrà àti ọ̀rọ̀ ìkínikáàbọ̀, ká sì máa fi ìtọ́ni tó tẹ̀lé e yìí sílò. Lẹ́yìn iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ pe ẹni tí ọpọ́n sún kàn.”
◼ Bí ẹ̀yin tẹ́ ẹ fẹ́ wá ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Igieduma bá tó ogún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó ṣe pàtàkì pé kẹ́ ẹ kọ́kọ́ kọ̀wé sí wa. Ẹ jọ̀wọ́ sọ iye ẹ̀yin tẹ́ ẹ̀ ń bọ̀ àti ọjọ́ tẹ́ ẹ máa wá. Ẹ sì tún lè tẹ̀ wá láago, ó pẹ́ tán, ọjọ́ méjì ṣáájú ọjọ́ tẹ́ ẹ̀ ń bọ̀. Ẹ kọ orúkọ àwọn akéde tó ti ṣèrìbọmi, àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi àti àwọn olùfìfẹ́hàn tó wà lára ẹ̀yin tẹ́ ẹ̀ ń bọ̀ sínú ìwé kan. Wọ́n á gba ìwé náà lọ́wọ́ yín bẹ́ ẹ bá dé Bẹ́tẹ́lì. Wákàtí méjì gbáko ló máa gbà yín láti rìn yíká ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, fún ìdí yìí, a rọ̀ yín láti tètè gbéra kẹ́ ẹ bàa lè débí lásìkò kẹ́ ẹ sì lè padà sílé lọ́jọ́ yẹn kan náà. Ohun tẹ́ ẹ máa kọ sórí lẹ́tà yín ni: “Attention Bethel Office.” Ṣáájú kẹ́ ẹ tó wá, ẹ jọ̀wọ́ ẹ ṣàtúnyẹ̀wò Àpótí Ìbéèrè tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 2002, tó sọ nípa irú aṣọ tó bójú mu àti ọ̀nà tó yẹ ká gbà múra nígbà tá a bá ń ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì.