Bá Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Ìtara Wa Dín Kù
1 Bí Àpólò ṣe fi ìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lè rán wa létí àwọn ará wa òde òní tí wọ́n ní ìtara tó gbóná lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù náà. (Ìṣe 18:24-28) Síbẹ̀, gbogbo wa ni ìmọ̀ràn yìí kàn pé: “Ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ àmójútó yín. Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú yín.” (Róòmù 12:11) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìtara? Báwo la sì ṣe lè máa bá a lọ ní fífi ìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni?
2 Ìtara Tí Ìmọ̀ Ń Sún Ṣiṣẹ́: Lẹ́yìn tí Jésù fara han méjì lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó sì “túmọ̀ àwọn nǹkan tí ó jẹ mọ́ ara rẹ̀ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ fún wọn,” wọ́n wí fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Ọkàn-àyà wa kò ha ń jó fòfò bí ó ti ń bá wa sọ̀rọ̀ ní ojú ọ̀nà?” (Lúùkù 24:27, 32) Lọ́nà kan náà, ṣé ọkàn tiwa náà kì í jó fòfò bí òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe túbọ̀ ń yé wa sí i? Òótọ́ pọ́ńbélé ni, ìmọ̀ ló ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹni pọ̀ sí i. Róòmù 10:17 ṣàlàyé pé: “Ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.” Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, kò sí bá ò ṣe ní máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a ti kọ́!—Sm. 145:7; Ìṣe 4:20.
3 Ìmọ̀ àtẹ̀yìnwá tá a ní nìkan ò lè mú kí ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run máa lágbára sí i kò sì lè mú kí ìtara tá a fi ń sìn ín gbóná tó bó ṣe yẹ. A gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti jẹ́ kí òye òtítọ́ tá a ní máa pọ̀ sí i ká sì jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà jinlẹ̀ sí i. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, kò ní pẹ́ tí ìjọsìn wa á fi di gbà-máà-póò-rọ́wọ́-mi. (Ìṣí. 2:4) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ká máa “pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run.”—Kól. 1:9, 10.
4 Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Kẹ́kọ̀ọ́: Ì bá dáa ká ṣàyẹ̀wò ọwọ́ tá a fi mú ìdákẹ́kọ̀ọ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, a lè máa fàlà sídìí ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ tá a máa kà nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ kí ìdáhùn wa sì máa dùn mọ̀ràn-ìn mọran-in. Ṣùgbọ́n, ṣé a máa ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fà yọ, ṣé a sì máa ń ṣàṣàrò lórí bó ṣe kàn wá? Nípa Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, ǹjẹ́ a máa ń sapá láti walẹ̀ jìn, bí ipò wa bá gbà bẹ́ẹ̀, ká sì ṣàṣàrò lórí àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ nínú àwọn orí Bíbélì náà? (Sm. 77:11, 12; Òwe 2:1-5) Àǹfààní tá a máa rí látinú fífẹ̀sọ̀ ronú àti fífi ara wa fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pátápátá ò lóǹkà! (1 Tím. 4:15, 16) Irú ìkẹ́kọ̀ọ́ tó nítumọ̀ bẹ́ẹ̀ máa gbé wa ró, ó sì máa fún wa lókun láti jẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà.”—Títù 2:14.