Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù July àti August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni la ó lò. Ká sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tá a bá bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀. Gbogbo àwọn tá a fún ní ìwé ni ká ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn ká sì ní ín lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó lò. Bí onílé bá nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó o bá a sọ, jọ̀wọ́ fún un ní ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà!
◼ Láti oṣù September lọ, ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo èèyàn tí àwọn alábòójútó àyíká máa bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ni, “Ṣé Ẹni Ìtẹ́wọ́gbà Lo Jẹ́ Lójú Ọlọ́run?”
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ January 8, 2007, ìwé Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀! la ó bẹ̀rẹ̀ sí í lò ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Káwọn ìjọ tètè rí i dájú pé àwọn ní iye tó tó lọ́wọ́ kó tó dìgbà tá a máa bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.
◼ A dábàá pé kẹ́ ẹ máa fi àwọn ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ó pẹ́ tán, lóṣù kan ṣáájú déètì tí akéde náà fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀. Kí akọ̀wé rí i pé àwọn ìsọfúnni tó wà nínú àwọn fọ́ọ̀mù náà pé pérépéré. Báwọn tó fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà ò bá lè rántí ọjọ́ tí wọ́n ṣèrìbọmi, kí wọ́n fojú bu déètì kan, kí wọ́n sì kọ ọ́ síbì kan. Kí akọ̀wé kọ déètì náà sórí káàdì Congregation’s Publisher Record (S-21), ìyẹn àkọsílẹ̀ akéde ìjọ.
◼ Kí àwọn akọ̀wé ìjọ máa rí i pé lẹ́tà tá a fi yan àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ, ìyẹn Pioneer Appointment Letter (S-202), wà lọ́wọ́. Bí ti aṣáájú-ọ̀nà èyíkéyìí ò bá sí nínú fáìlì ìjọ, kí akọ̀wé kọ lẹ́tà láti béèrè ní ẹ̀ka ọ́fíìsì.
◼ Ní August 31, 2006 tàbí kó máà pẹ́ sígbà yẹn, kí ẹ ka gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́, bá a ti ń ṣe lọ́dọọdún. Ìṣirò yìí jọ èyí tí olùṣekòkáárí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ máa ń ṣe lóṣooṣù nípa kíka àwọn ìwé náà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Kẹ́ ẹ kọ iye tí wọ́n jẹ́ sórí fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18). Ẹ ní kí (àwọn) ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé ìròyìn sọ àròpọ̀ iye ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ fún yín. Kí akọ̀wé ìjọ tó ń ṣe kòkáárí bójú tó ìṣirò ọlọ́dọọdún náà. Akọ̀wé àti alága àwọn alábòójútó ìjọ tó ń ṣe kòkáárí ni kó fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà. Gbogbo ìjọ tó ń ṣe kòkáárí yóò gba fọ́ọ̀mù Literature Inventory mẹ́ta-mẹ́ta. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ẹ̀dà àkọ́kọ́ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ó pẹ́ tán ní September 6. Ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì yín. Ẹ lè lo ẹ̀dà kẹta láti fi ṣírò ìwé tó wà lọ́wọ́.
◼ A fi fọ́ọ̀mù nípa àwọn tó mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, ìyẹn Literacy Report, méjì-méjì ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. Bẹ́ ẹ bá ti kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù méjèèjì, ẹ jọ̀wọ́ ẹ fi ẹ̀dà kan ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní August 1. Kẹ́ ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì ìjọ.