Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni la ó lò. Ká sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tá a bá bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀. Gbogbo àwọn tá a fún ní ìwé ni ká ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn ká sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó lò. Bí onílé bá nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó o bá a sọ, jọ̀wọ́ fún un ní ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! November: Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Báwọn kan bá sọ pé àwọn kì í ṣe òbí, ẹ fún wọn ní ìwé àṣàrò kúkúrú Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú míì tó bá yẹ.
◼ Kí alága àwọn alábòójútó tàbí ẹnì kan tó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní September 1 tàbí bó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà. Bẹ́ ẹ bá ní àkáǹtì mìíràn tẹ́ ẹ̀ ń tọ́jú owó sí fún bíbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, kó ṣàyẹ̀wò èyí pẹ̀lú. Bó bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó ti oṣù tó ń bọ̀.
◼ Kí àwọn alàgbà rántí láti kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù Kingdom Hall Maintenance Checklist (CN-14), kí wọ́n buwọ́ lù ú kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣáájú tàbí ní August 31. Kí wọ́n tún ṣètò láti rí i pé àwọn ṣe àyẹ̀wò ipò tí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà wà níbẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn tó ń bọ̀. Kí àwọn alàgbà rí i pé àwọn tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú fọ́ọ̀mù yẹn àtèyí tó wà nínú lẹ́tà tá a kọ sí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ní May 13, 2004.
◼ Ike Ìkósọfúnnisí Tuntun Tó Wà:
Beware of Losing Faith by Drawing Away From Jehovah (Àwòkẹ́kọ̀ọ́, ike pẹlẹbẹ méjì ló wà nínú rẹ̀)—Faransé
Jehovah Delivers Those Calling Upon His Name (Àwòkẹ́kọ̀ọ́, ike pẹlẹbẹ kan ló wà nínú rẹ̀)—Faransé
Jehovah’s Name to Be Declared in All the Earth (Àwòkẹ́kọ̀ọ́, ike pẹlẹbẹ kan ló wà nínú rẹ̀)—Faransé
Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? (ike pẹlẹbẹ méje ló wà nínú rẹ̀)—Gẹ̀ẹ́sì
Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? (ike pẹlẹbẹ méjì ló wà nínú rẹ̀)—Faransé
Watchtower Library —2005 Edition—Gẹ̀ẹ́sì