ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/06 ojú ìwé 7
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 10/06 ojú ìwé 7

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nígbà àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní October 30, 2006. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tó dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ September 4 sí October 30, 2006. [Àkíyèsí: Níbi tá ò bá ti sọ ibi tá a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ

1. Kí nìdí tí ìbàlẹ̀ ọkàn fi ṣe pàtàkì béèyàn bá ń sọ̀rọ̀, báwo lèèyàn sì ṣe lè dín àyà jíjá kù? [be-YR ojú ìwé 135 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 137 ìpínrọ̀ 2 àtàwọn àpótí]

2. Nígbà táwọn èèyàn bá bi wá nípa ohun tá a gbà gbọ́, kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti fi Bíbélì dá wọn lóhùn? [be-YR ojú ìwé 143 ìpínrọ̀ 1 sí 3]

3. Kí la lè ṣe ká bàa lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu lílo Bíbélì? [be-YR ojú ìwé 144 àti àpótí]

4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa lo Bíbélì lemọ́lemọ́ nígbà tá a bá ń kọ́ni lóde ẹ̀rí, ọ̀nà wo la sì lè gbà fúnni níṣìírí láti máa lò ó bẹ́ẹ̀ nínú ìpàdé ìjọ? [be-YR ojú ìwé 145 sí 146 àtàwọn àpótí]

5. Nǹkan méjì wo la fẹ́ ṣe tá a bá ń nasẹ̀ Ìwé Mímọ́? [be-YR ojú ìwé 147 ìpínrọ̀ 2]

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ

6. Ìkìlọ̀ wo ni Sáàmù karùnléláàádọ́rin fún wa nípa ìgbéraga? [w86-YR 12/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 7]

7. Kí ni “ìbẹ̀rù Jèhófà”? [w87-YR 5/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 3 sí 4]

8. Kí làwọn ohun méje tó jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún Jèhófà? (Òwe 6:16-19) [w87-YR 5/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 12]

9. Gẹ́gẹ́ bí Òwe 2:1-5, ṣe sọ, kí ló túmọ̀ sí láti máa wá ìmọ̀, òye àti ìfòyemọ̀ bí ẹni ń wá ‘fàdákà àti bí ẹní ń wá àwọn ìṣúra fífarasin’? [be-YR ojú ìwé 38 ìpínrọ̀ 4]

10. Ọ̀nà wo ni ríran àwọn ẹni rírẹlẹ̀ lọ́wọ́ fi dà bí ìgbà téèyàn wín Jèhófà? [w87-YR ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 14 sí 15]

BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀

11. Ọ̀nà wo ni Dáfídì gbà ‘tu ọkàn ara rẹ̀ lára pẹ̀sẹ̀, tó sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́ bí ọmọ tí a já lẹ́nu ọmú,’ báwo la sì ṣe lè fara wé e? (Sm. 131:1-3)

12. Ìtùnú wo la lè rí nínú ọ̀rọ̀ onímìísí tó wà nínú Sáàmù 139:7-12?

13. Gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 145 ṣe sọ, kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe jẹ́ oníṣẹ́ àrà, èyí tá a lè máa tìtorí rẹ̀ yìn ín nígbà tá a bá ń gbàdúrà tàbí tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá? (Sm. 145:3)

14. Ọ̀nà wo ni ìbẹ̀rù Jèhófà gbà jẹ́ “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìmọ̀” àti “ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n”? (Owe 1:7; 9:10)

15. Kí ni ìtumọ̀ “àsọjáde mi” àti “àṣẹ mi” bó ṣe wà nínú Òwe 7:1, 2?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́