Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù November: Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà la máa lò fáwọn tó ń tọ́mọ lọ́wọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ká fún wọn ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú mìíràn tó bá yẹ. December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Àwọn ìwé tá a lè lò bí àfirọ́pò ni Iwe Itan Bibeli Mi, tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. January: A lè lo ìwé èyíkéyìí tá a tẹ̀ ṣáájú ọdún 1991. Ìwé tá a lè lò bí àfirọ́pò: Ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! February: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà la máa lò. Ìwé tá a lè lò bí àfirọ́pò ni: Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀! tàbí ìwé mìíràn tó bá ti pọ̀ jù lọ́wọ́.
◼ Àtúnṣe ti bá ìwé náà, Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù sí Dẹ̀dẹ̀! Orúkọ tuntun tá a ó máa fi pè é ní báyìí ni Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù Sí Dẹ̀dẹ̀! Kí gbogbo ìjọ tó ń sọ èdè Yorùbá tètè jẹ́ ká mọ iye tí ìjọ wọn máa nílò. Ní gbàrà tí ìwé náà bá ti dé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Igieduma la ó fi iye tẹ́ ẹ béèrè ránṣẹ́ sí yín.