Àwọn Ìbéèrè Tá a Máa Lò Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
Bá a ṣe máa lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
Kó o bàa lè kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí lọ́nà tó gbámúṣé, á dáa kó o kọ nọ́ńbà sáwọn ìpínrọ̀ tó wà ní orí kọ̀ọ̀kan, títí kan àwọn ìpínrọ̀ tó wà nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú. Gbogbo ìpínrọ̀ tó bá wà nínú ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan ni kó o sì máa kà pa pọ̀. Bẹ́ ẹ bá ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ, ẹ lè jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà ní ìparí orí kọ̀ọ̀kan nígbà tó bá yẹ.
Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ka ìwé yìí ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, orí méjì ni kẹ́ ẹ máa kà lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, kẹ́ ẹ fi ọ̀rọ̀ ìṣáájú ṣe orí kìíní. Ọ̀sẹ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lẹ máa fi kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìwé yìí, kẹ́ ẹ fi ọ̀sẹ̀ tó bá kẹ́yìn jíròrò Orí 48 tó gbẹ̀yìn pẹ̀lú àtúnyẹ̀wò ráńpẹ́ nínú ìwé yìí.
Ọ̀rọ̀ ìṣáájú Ìpínrọ̀ 1 sí 5
1. Kí nìdí táwọn èèyàn fi ka ọmọ bíbí sí iṣẹ́ ìyanu ńlá?
2. Àwọn nǹkan wo làwọn ọmọ nílò látọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn?
3. Kí nìdí táwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni fi gbọ́dọ̀ máa gbé àwọn ìtọ́sọ́nà tí wọ́n ń fún àwọn ọmọ wọn karí Bíbélì dípò ọgbọ́n orí èèyàn tàbí àṣà ìbílẹ̀ wọn? (Òwe 3:5, 6; 14:12; Aísáyà 30: 21)
Ìpínrọ̀ 6 sí 10
4. Báwo la ṣe ṣe àwọn ìbéèrè tó wà nínú ìwé yìí kó lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́, kí sì làwọn òbí máa mọ̀ látinú ìdáhùn àwọn ọmọ náà?
5. Báwo la ṣe ṣe àwọn àwòrán inú ìwé yìí lọ́nà tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́?
6. Kí nìdí tá a fi ṣe ìwé yìí?
Orí 1 Ìpínrọ̀ 1 sí 6
1. Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, àwọn nǹkan wo ni Jésù lè ṣe?
2. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ Ọmọ rere tó sì tún di Olùkọ́ Ńlá?
3. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà yàtọ̀ sáwọn èèyàn yòókù láyé?
Ìpínrọ̀ 7 sí 11
4. Báwo làwọn ọmọ kéékèèké ṣe mọ̀ pé Jésù fẹ́ràn àwọn?
5. Kí nìdí tí Jésù fi máa ń kọ́ àwọn ọmọdé lẹ́kọ̀ọ́, kí làwa náà sì lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ rẹ̀?
6. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé káwọn àgbàlagbà dà bí ọmọ kékeré?
Ìpínrọ̀ 12 sí 16
7. Kí lohun tí Jésù fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹyẹ àtàwọn òdòdó?
8. Báwo lohun tí Jésù fi kọ́ni yìí ṣe lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti pinnu bóyá kí òun lọ máa ṣiṣẹ́ tó máa mú kí òun lọ máa gbé lọ́nà tó jìn sí ìdílé rẹ̀?
9. Kí lo rí nínú Ìwàásù Jésù lórí Òkè tó fi hàn pé ó ṣe pàtàkì láti máa fi Ọlọ́run ṣáájú nínú ìgbésí ayé wa?
Ìpínrọ̀ 17 sí 21
10. Ọ̀nà wo la lè gbà fetí sí Jésù, kí ni ṣíṣe bẹ́ẹ̀ sì máa yọrí sí?
11. Nígbà wo ni Ọlọ́run sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù pé kí wọ́n fetí sí i, báwo la sì ṣe lè ní ojúlówó ayọ̀?
Orí 2 Ìpínrọ̀ 1 sí 7
1. Kí ló mú kí Bíbélì ṣe pàtàkì ju gbogbo àwọn ìwé yòókù lọ?
2. Báwo ni Ọlọ́run ṣe mú kí wọ́n kọ Bíbélì, kí sì nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run lè fi ìsọfúnni ránṣẹ́ láti ọ̀run?
Ìpínrọ̀ 8 sí 12
3. Ta lẹni àkọ́kọ́ tó kọ lára Bíbélì, ó sì tó ọdún mélòó tí wọ́n fi kọ ọ́?
4. Dárúkọ díẹ̀ lára àwọn tó kọ Bíbélì, kó o sì sọ ibi tí wọ́n wà nínú àwòrán yìí.
5. Báwo làwọn tó kọ Bíbélì ṣe mọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú kó tó ṣẹlẹ̀?
Ìpínrọ̀ 13 sí 18
6. Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo èèyàn láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú lẹ́tà tí Ọlọ́run kọ sí aráyé?
7. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun pàtàkì tí Bíbélì sọ fún wa?
8. Báwo la ṣe lè fi hàn pé lóòótọ́ la jẹ́ ọlọ́gbọ́n tá a sì mọrírì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
Orí 3 Ìpínrọ̀ 1 sí 10
1. Kí ló wú ẹ lórí nínú ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá wa?
2. Ta lẹni tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, báwo la sì ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
3. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá àwọn ohun ẹlẹ́mìí?
4. Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí wa?
Ìpínrọ̀ 11 sí 21
5. Àwọn àpẹẹrẹ wo lo lè fi ṣàlàyé pé Ọlọ́run wà lóòótọ́?
6. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ gbẹ́ ère Ọlọ́run?
7. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a moore Ọlọ́run?
Orí 4 Ìpínrọ̀ 1 sí 6
1. Kí ló fi hàn pé orúkọ ṣe pàtàkì gan-an?
2. Kí ni orúkọ Ọlọ́run, kí sì nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa lò ó?
3. Báwo ni Jésù ṣe lo orúkọ Ọlọ́run tó sì tún kọ́ àwọn míì láti máa ṣe bẹ́ẹ̀?
Ìpínrọ̀ 7 sí 14
4. Kí lohun tí Ọlọ́run sọ fún Mósè nípa orúkọ Rẹ̀?
5. Kí ni Jèhófà sọ fún Fáráò nípa orúkọ Rẹ̀?
6. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ rẹ̀ nígbà yẹn, báwo ló sì ṣe ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ ọ́n lónìí?
Ìpínrọ̀ 15 sí 19
7. Níbo ni orúkọ Ọlọ́run wà nínú Bíbélì rẹ?
8. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
Orí 5 Ìpínrọ̀ 1 sí 8
1. Kí nìdí tá a fi bí Jésù gẹ́gẹ́ bí ọmọ jòjòló sórí ilẹ̀ ayé? (Lúùkù 1:26-38)
2. Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni Jésù àti Màríà fi lélẹ̀, báwo la sì ṣe lè fara wé wọn?
3. Kí ló mú kí ìbí Jésù yàtọ̀ sí ti gbogbo èèyàn?
Ìpínrọ̀ 9 sí 17
4. Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ tí Màríà bí Jésù?
5. Ibo ni Jésù dàgbà sí, kí lohun tó sì ṣe tí inú Ọlọ́run fi dùn sí i? (Sáàmù 40:6-8)
6. Àwọn nǹkan míì wo la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù?
Orí 6 Ìpínrọ̀ 1 sí 4
1. Kí lohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fẹ́, báwo sì làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe fi hàn pé àwọn náà nírú èrò yẹn nígbà kan?
2. Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àmọ́ tí wọ́n kọ̀ láti fi sọ́kàn nígbà tó kọ́kọ́ kọ́ wọn?
Ìpínrọ̀ 5 sí 11
3. Kí ni Jésù ṣe lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, kí sì nìyẹn kọ́ wa?
4. Tá a bá tẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù, àwọn àbájáde rere wo nìyẹn máa mú wá?
Ìpínrọ̀ 12 sí 17
5. Báwo lo ṣe lè sin àwọn tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìdílé?
6. Báwo lo ṣe lè sin àwọn èèyàn nílé ìwé àti láwọn ibòmíì?
7. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ fà sẹ́yìn nínú sísin àwọn ẹlòmíì àní bí wọn ò bá tiẹ̀ fi hàn pé àwọn moore?
Orí 7 Ìpínrọ̀ 1 sí 9
1. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká máa ṣègbọràn sáwọn tó dàgbà jù wá lọ?
2. Kí la lè rí kọ́ látinú àdúrà tí Jésù gbà nínú Lúùkù 22:42?
3. Kí là ń fi hàn tá a bá ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run?
Ìpínrọ̀ 10 sí 15
4. Báwo làwọn ọmọdé ṣe lè fi ohun tó wà nínú Éfésù 6:1-3 sílò, kí sì nìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀?
5. Báwo ni ìgbọ́ràn ṣe dáàbò bo àwọn kan láyé àtijọ́?
Ìpínrọ̀ 16 sí 19
6. Báwo ni ìgbọ́ràn ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọdé lónìí?
7. Báwo ni gbogbo wa ṣe máa jàǹfààní látinú ṣíṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run?
Orí 8 Ìpínrọ̀ 1 sí 5
1. Àwọn wo ló wà nípò tó ga tí wọ́n sì lágbára ju àwa èèyàn lọ?
2. Iṣẹ́ ìyanu wo ni Ọlọ́run ṣe kí wọ́n lè bí Jésù sáyé gẹ́gẹ́ bí ọmọ jòjòló?
3. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun ti wà tẹ́lẹ̀ kí òun tó wá sáyé bí èèyàn?
Ìpínrọ̀ 6 sí 11
4. Ká ní Ádámù àti Éfà ṣègbọràn sí Ọlọ́run ni, irú ọjọ́ iwájú wo ni wọn ì bá ti gbádùn?
5. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ látinú Jẹ́nẹ́sísì 2:17?
Ìpínrọ̀ 12 sí 19
6. Báwo ni áńgẹ́lì kan tí Ọlọ́run dá ṣe tan Éfà jẹ?
7. Kí ló ṣẹlẹ̀ nítorí àìgbọràn tí Ádámù àti Éfà ṣe sí Ọlọ́run?
8. Kí nìdí tí áńgẹ́lì rere kan fi di áńgẹ́lì burúkú?
9. Báwo la ṣe lè fara wé Jésù ká sì fi hàn pé irọ́ ni Èṣù ń pa?
Orí 9 Ìpínrọ̀ 1 sí 4
1. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ ká sì ṣe ohun tó burú nígbà tí ẹnì kan bá dán wa wò?
2. Kí lọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ pé “ọ̀run ṣí sílẹ̀” nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí?
Ìpínrọ̀ 5 sí 13
3. Báwo ni Sátánì ṣe kọ́kọ́ dẹ Jésù wò, báwo sì ni Jésù ṣe kọ̀ láti juwọ́ sílẹ̀?
4. Kí lohun kejì tí Sátánì fi dẹ Jésù wò, báwo sì ni Jésù ṣe dá a lóhùn?
5. Kí la lè rí kọ́ látinú ìdẹwò kẹta tí Èṣù gbé síwájú Jésù?
Ìpínrọ̀ 14 sí 20
6. Báwo la ṣe lè dẹni tá a dẹ wò láti tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wa lọ́rùn tàbí láti ṣe ohun tí kò bọ́gbọ́n mu?
7. Ìgbà wo ló máa ń ṣòro láti ṣe ohun tó tọ́, àmọ́ kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀?
Orí 10 Ìpínrọ̀ 1 sí 6
1. Kí ló mú kí ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì di alátakò Ọlọ́run?
2. Kí làwọn áńgẹ́lì míì tún ṣe, kí sì nìdí tí ohun tí wọ́n ṣe yẹn fi burú?
3. Báwo làwọn ọmọ táwọn áńgẹ́lì yìí bí ṣe rí, kí ni Ọlọ́run sì ṣe nítorí ipò búburú tí ayé wà nígbà yẹn?
Ìpínrọ̀ 7 sí 11
4. Kí lohun tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń ṣe báyìí, ipa wo ni wọ́n sì lè ní lórí wa?
5. Kí làwọn nǹkan burúkú táwọn áńgẹ́lì búburú máa ń mú káwọn ọmọdé ṣe?
Ìpínrọ̀ 12 sí 17
6. Kí làwọn ohun burúkú táwọn áńgẹ́lì búburú nífẹ̀ẹ́ sí, ibo làwọn èèyàn sì ti sábà máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan wọ̀nyẹn?
7. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀mí èṣù lágbára, kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù wọn?
Orí 11 Ìpínrọ̀ 1 sí 11
1. Kí nìdí tá a fi lè gba àwọn nǹkan tá ò lè fojú rí gbọ́?
2. Kí làwọn ohun tá a ti kọ́ nípa àwọn áńgẹ́lì rere àti búburú?
3. Ǹjẹ́ o gbà pé àwọn áńgẹ́lì máa ń sọ̀rọ̀ nípa wa, kí ni wọ́n máa ń sọ?
4. Báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́ láyé àtijọ́?
Ìpínrọ̀ 12 sí 17
5. Iṣẹ́ pàtàkì wo làwọn áńgẹ́lì ń ṣe nítorí àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run tá a wà láyé?
6. Iṣẹ́ wo làwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ti Pọ́ọ̀lù lẹ́yìn láti ṣe?
7. Iṣẹ́ ńlá wo làwọn áńgẹ́lì máa bá Ọlọ́run ṣe láìpẹ́?
Orí 12 Ìpínrọ̀ 1 sí 7
1. Kí là ń pè ní àdúrà, báwo la sì ṣe mọ̀ pé kò burú tá a bá gbàdúrà láwa nìkan tàbí nígbà tá a bá wà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì?
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe “Àmín” lẹ́yìn àdúrà, kí sì ni ṣíṣe bẹ́ẹ̀ túmọ̀ sí?
3. Nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà ní ìpàdé ìjọ, kí nìdí tó fi yẹ ká máa fetí sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ká má sì máa wò káàkiri tàbí ká máa pariwo?
4. Kí la rí kọ́ nínú àdúrà tí Nehemáyà gbà?
Ìpínrọ̀ 8 sí 10
5. Ohun pàtàkì wo la gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn nípa àdúrà?
6. Àwọn nǹkan wo la lè sọ nígbà tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run?
Ìpínrọ̀ 11 sí 17
7. Àwọn ohun mẹ́ta wo ló ṣe pàtàkì jù lọ tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n gbàdúrà fún?
8. Àwọn nǹkan míì wo ni Jésù sọ pé ká máa gbàdúrà fún?
Orí 13 Ìpínrọ̀ 1 sí 7
1. Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù?
2. Àwọn mẹ́fà wo ló kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, kí lo sì mọ̀ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn?
3. Àwọn mẹ́rin wo ló padà sẹ́nu iṣẹ́ ẹja pípa lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe dáhùn nígbà tí Jésù tún pè wọ́n láti máa tọ òun lẹ́yìn?
Ìpínrọ̀ 8 sí 12
4. Lẹ́yìn táwọn ọkùnrin yìí ti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, kí ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa múra tán láti ṣe?
5. Ta ló kọ̀ láti di ọmọ ẹ̀yìn nígbà tí Jésù pè é, kí sì nìdí?
6. Àwọn méjìlá wo ni Jésù yàn láti di àpọ́sítélì rẹ̀?
7. Èwo nínú àwọn àpọ́sítélì méjìlá yìí ló di aláìṣòótọ́, ta ni wọ́n sì yàn rọ́pò rẹ̀?
8. Àwọn ọkùnrin wo ló tún di àpọ́sítélì?
Ìpínrọ̀ 13 sí 16
9. Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn obìnrin lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù?
10. Báwo ni ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ yóò ṣe máa hùwà, ibo ni yóò sì ti máa hu irú ìwà bẹ́ẹ̀?
Orí 14 Ìpínrọ̀ 1 sí 5
1. Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn tó bá ṣe ohun tó dùn wá?
2. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé, ká máa ‘dárí jini títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje’?
3. Kí ni Jésù ṣe lẹ́yìn tó dáhùn ìbéèrè Pétérù?
Ìpínrọ̀ 6 sí 13
4. Kí ni ọba kan ṣe fún ẹrú kan tó jẹ ẹ́ lówó tó pọ̀ gan-an?
5. Kí ni ẹrú yẹn ṣe fún ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó jẹ ẹ́ ní owó tí kò tó nǹkan?
6. Kí ni ọba ṣe nígbà tó gbọ́ ohun tí ẹrú tí kò dárí jini yẹn ṣe?
Ìpínrọ̀ 14 sí 18
7. Nínú ìtàn tí Jésù sọ yìí, ta ni ọba yẹn dúró fún?
8. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ló wà nínú ìtàn tí Jésù sọ yìí?
9. Ká sọ pé o ti dárí ji ẹnì kan lọ́pọ̀ ìgbà, tó tún wá ṣe ohun tó dùn ẹ́, ṣé wàá tún dárí jì í?
Orí 15 Ìpínrọ̀ 1 sí 7
1. Kí ló ń jẹ́ ẹ̀tanú, kí sì nìdí tó o fi gbà pé kò dára kéèyàn ní in?
2. Nígbà tí ọkùnrin ẹlẹ́tanú kan báyìí béèrè ohun tóun lè ṣe láti wà láàyè títí láé lọ́wọ́ Jésù, kí ni Jésù kọ́kọ́ sọ fún un?
3. Báwo ni ọkùnrin yìí ṣe ṣe àwáwí nítorí pé kò fẹ́ ṣe inú rere sáwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà tirẹ̀?
Ìpínrọ̀ 8 sí 15
4. Ìtàn wo ni Jésù sọ fún ọkùnrin yẹn láti ràn án lọ́wọ́?
5. Ìbéèrè wo ni Jésù bi ọkùnrin yẹn lẹ́yìn tó parí ìtàn náà, báwo ló sì ṣe dáhùn?
Ìpínrọ̀ 16 sí 19
6. Báwo ni ìtàn tí Jésù sọ ṣe jẹ́ ká mọ ẹni tó jẹ́ aládùúgbò wa?
7. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà kì í ṣe ẹ̀tanú?
8. Báwo la ṣe lè jẹ́ aládùúgbò rere?