ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/08 ojú ìwé 2-7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 4/08 ojú ìwé 2-7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ẹ sapá lákànṣe láti ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fìfẹ́ hàn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tí wọ́n sì tún wá gbọ́ àkànṣe àsọyé àmọ́ tí wọn kì í wá sípàdé ìjọ déédéé. Ìdí tẹ́ ẹ fi fẹ́ padà bẹ̀ wọ́n wò ni láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. June: Ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. July àti August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Ẹmi Awọn Oku-Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Ìwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun-Ṣé O Ti Rí I? àti “Sáwo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.”

◼ Kí àwọn akọ̀wé ìjọ máa rí i pé Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà Déédéé (S-205-YR) àti Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ (S-205b-YR) tó pọ̀ tó wà lọ́wọ́. Ẹ lè béèrè fún àwọn fọ́ọ̀mù yìí nípa lílo fọ́ọ̀mù tá a fi ń béèrè ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn Literature Request Form (S-14). Kẹ́ ẹ rí i pé èyí tí ìjọ ní lọ́wọ́ máa tó lò fún ọdún kan, ó kéré tán. Ẹ máa ṣàyẹ̀wò gbogbo fọ́ọ̀mù ìwọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé láti rí i dájú pé ìsọfúnni inú wọn pé pérépéré kẹ́ ẹ tó fi wọ́n ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì.

◼ Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa níbí ní àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù tí gbogbo alága àwọn alábòójútó àti akọ̀wé ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́. Bí ìyípadà bá wà nígbàkigbà, kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ kọ àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù tí wọ́n ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ sínú fọ́ọ̀mù tá a máa ń kọ ìsọfúnni sí nípa ìyípadà àdírẹ́sì alága àwọn alábòójútó àti akọ̀wé, ìyẹn Presiding Overseer/Secretary Change of Address (S-29), kí wọ́n buwọ́ lù ú, kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì lọ́gán. Èyí kan ìyípadà tó bá wà nínú nọ́ńbà tẹ́ni tó bá fẹ́ pe àdúgbò wọn gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ tẹ̀, ìyẹn area codes, kó tó tẹ nọ́ńbà tó fẹ́ pè.

◼ Nígbàkigbà tó o bá ń ṣètò fúnra rẹ láti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, tó o sì fẹ́ lọ sí ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àgbègbè níbẹ̀, ọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè náà ni kó o ti béèrè déètì, àkókò àti ibi tí wọ́n á ti ṣe ìpàdé ọ̀hún. Àdírẹ́sì àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wà ní ojú ìwé tó kẹ́yìn nínú ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn Yearbook tọdún yìí.

◼ Ní May 30 àti 31, ọdún 2008, kò ní sáyè fún wa láti gbàlejò ní Bẹ́tẹ́lì. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣèbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ ni kẹ́ ẹ má ṣe wá gba ìwé láwọn ọjọ́ wọ̀nyí.

◼ Àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí pọ̀ rẹpẹtẹ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa níbí, à ń fẹ́ káwọn akéde tó bá máa nílò wọn lóde ẹ̀rí tàbí tí wọ́n fẹ́ fi síbi ìkówèésí wọn lọ forúkọ sílẹ̀ nínú ìjọ wọ́n:

Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run—Ísókó

Sún Mọ́ Jèhófà—Ẹ́fíìkì, Ìgbò àti Ísókó

Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní—Ẹ́fíìkì

Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì—Ẹ́fíìkì, Gẹ̀ẹ́sì àti Ìgbò

Ẹ Máa Ṣọ́nà!—Ísókó

Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ísókó àti Tífí

Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà—Ìgbò

Ki Ni Ète Igbesi-Aye?—Ísókó

Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà—Ẹ́fíìkì, Gẹ̀ẹ́sì, Ìgbò, Ísókó àti Yorùbá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́