Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò tó wà nísàlẹ̀ yìí la óò gbé yẹ̀ wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní June 30, 2008. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ May 5 sí June 30, 2008, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sì darí rẹ̀ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú.
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Kí la lè ṣe kí àpèjúwe tá a bá lò lè yé àwọn èèyàn? [be-YR ojú ìwé 242 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 243 ìpínrọ̀ 1]
2. Kí nìdí tí lílo àpèjúwe tó rọrùn tó sì dá lórí ohun táwọn olùgbọ́ wa mọ̀ dáadáa fi máa ń gbéṣẹ́? [be-YR 245 ojú ìwé 2 sí 4]
3. Báwo ni lílo àwọn nǹkan tá a lè fojú rí láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ṣe gbẹ́ṣẹ́ tó, báwo sì ni Jèhófà ṣe lò wọ́n láti kọ́ àwọn èèyàn láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan? (Jẹ́n. 15:5; Jer. 18:6; Jónà 4:10, 11) [be-YR ojú ìwé 247 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
4. Báwo ni lílo àwọn ohun tá a lè fojú rí ṣe lè mú kí ọ̀nà tá a gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ múná dóko? [be-YR ojú ìwé 248 ìpínrọ̀ 1 sí 3]
5. Báwo la ṣe lè lo àwòrán ilẹ̀ nígbà tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? [be-YR ojú ìwé 248 ìpínrọ̀ 4]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Kí ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ bá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? [be-YR ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 3 àti 4]
7. Báwo la ṣe lè lo Bíbélì láti ṣèwádìí lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan? [be-YR ojú ìwé 34 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 35 ìpínrọ̀ 2]
8. Báwo ni ojúṣe Jésù gẹ́gẹ́ bí Olùṣọ́ Àgùntàn Rere tó ń bójú tó àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó níwà tútù bí àgùntàn ṣe fi hàn pé ó bìkítà nípa àwọn èèyàn? [w90-YR 3/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2]
9. Àwọn ẹ̀rí wo nínú Ìwé Mímọ́ ló fi hàn pé Lúùkù tó jẹ́ oníṣègùn ló kọ ìwé Ìṣe tó wà nínú Bíbélì? [w90-YR 5/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 3 àti 5]
10. Báwo ni gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣe lè ṣe ìlapa èrò tiwa tá a bá fẹ́ sọ àsọyé? [be-YR ojú ìwé 39 sí 41]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Tẹ́ńpìlì wo ni wọ́n fi “ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta” kọ́? (Jòh. 2:20) [w08-YR 4/15 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jòhánù”]
12. Àwọn wo ló ń “ré kọjá láti inú ikú sínú ìyè”? (Jòh. 5:24, 25) [w08-YR 4/15 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jòhánù”]
13. Báwo ni Jésù ṣe máa “pèsè ibì kan sílẹ̀” ní ọ̀run fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́? (Jòh. 14:2) [w08-YR 4/15 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jòhánù”]
14. Kí nìdí tí Jésù fi sọ fún Màríà Magidalénì pé kó dẹ́kun dídìrọ̀ mọ́ òun? (Jòh. 20:17) [w08-YR 4/15 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jòhánù”]
15. Kí ló túmọ̀ sí pé “irú ọ̀nà kan náà” tí Jésù gbà lọ sọ́run náà ló máa gbà padà wá? (Ìṣe 1:9-11) [gt-YR orí 131 ìpínrọ̀ 8 àti 9; it-1-E ojú ìwé 186 ìpínrọ̀ 8]