ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/08 ojú ìwé 2-3
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 7/08 ojú ìwé 2-3

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù July àti August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Ẹmi Awọn Oku-Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Ìwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun-Ṣé O Ti Rí I? àti “Sáwo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́jọ́ tẹ́ ẹ kọ́kọ́ bá onílé sọ̀rọ̀. Tí onílé bá sì ti ní ìwé yìí, ẹ fi bó ṣe lè jàǹfààní látinú rẹ̀ hàn án nípa jíjẹ́ kó mọ bá a ṣe ń fi ìwé náà ṣèkẹ́kọ̀ọ́ àwọn èèyàn. October: Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Bí ẹni náà bá fìfẹ́ hàn, fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì?, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò rẹ̀, ní ín lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.

◼ Níwọ̀n bí oṣù August ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa dáa gan-an láti fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

◼ Bẹ̀rẹ̀ láti September, àkòrí àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni “Máa Rìn Lọ́nà Ìwà Títọ́.”

◼ A dábàá pé kẹ́ ẹ máa fi àwọn ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ó pẹ́ tán, lóṣù kan ṣáájú déètì tí akéde náà fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀. Kí akọ̀wé rí i pé àwọn ìsọfúnni tó wà nínú àwọn fọ́ọ̀mù náà pé pérépéré. Bẹ́ni tó fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà ò bá rántí ọjọ́ tó ṣèrìbọmi, kó fojú bu déètì kan, kó sì kọ ọ́ síbì kan. Kí akọ̀wé kọ déètì náà sórí káàdì Congregation’s Publisher Record (S-21), ìyẹn àkọsílẹ̀ akéde ìjọ.

◼ Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa níbí kì í fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sí akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alága àwọn alábòójútó rí i pé ìjọ ń ṣèfilọ̀ lóṣooṣù kí wọ́n tó fi fọ́ọ̀mù tá a fi ń béèrè ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ nílò lóṣù kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, kí olúkúlùkù ẹni tó bá fẹ́ gba ìwé sọ fún arákùnrin tó ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ má sì gbàgbé pé àwọn ìtẹ̀jáde kan wà tá a máa ń béèrè fún lákànṣe.

◼ Ní August 31, 2008 tàbí kó máà pẹ́ sígbà yẹn, kẹ́ ẹ ka gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́, bá a ti ń ṣe lọ́dọọdún. Ìṣirò yìí jọ èyí tí olùṣekòkáárí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ máa ń ṣe lóṣooṣù nípa kíka àwọn ìwé náà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Kẹ́ ẹ kọ iye tí wọ́n jẹ́ sórí fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18). Ẹ ní kí (àwọn) ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé ìròyìn sọ àròpọ̀ iye ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ fún yín. Kí akọ̀wé ìjọ tó ń ṣe kòkáárí bójú tó ìṣirò ọlọ́dọọdún náà. Akọ̀wé àti alága àwọn alábòójútó ìjọ tó ń ṣe kòkáárí ni kó buwọ́ lu fọ́ọ̀mù náà. Gbogbo ìjọ tó ń ṣe kòkáárí yóò gba fọ́ọ̀mù Literature Inventory mẹ́ta-mẹ́ta. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ẹ̀dà àkọ́kọ́ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ó pẹ́ tán ní September 6. Ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì ìjọ. Ẹ lè lo ẹ̀dà kẹta láti fi ṣírò ìwé tó wà lọ́wọ́.

◼ A fi fọ́ọ̀mù mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, ìyẹn Literacy Report, méjì-méjì ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. Bẹ́ ẹ bá ti kọ ohun tó yẹ sínú fọ́ọ̀mù méjèèjì, ẹ fi ẹ̀dà kan ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní August 1. Kẹ́ ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì ìjọ.

◼ Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ni kẹ́ ẹ máa fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́, òun náà sì ni kẹ́ ẹ máa fi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ dípò ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Ẹ ṣì lè máa fìwé Béèrè sóde títí tó fi máa tán lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́