Jẹ́ Olóòótọ́ Nípa Jíjẹ́ Akéde Tó Ń Ṣe Déédéé
1 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ nípa àkókò òpin, ó tẹ́nu mọ́ ọn pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, a ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Máàkù 13:10) Jésù tipa báyìí jẹ́ kó ṣe kedere pé iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn ló gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì jù lọ sáwọn ọmọ ẹ̀yìn tó máa wà láyé nígbà wíwàníhìn-ín òun, wọ́n gbọ́dọ̀ fi ṣáájú ohunkóhun mìíràn, wọ́n sì gbọ́dọ̀ máa ṣe é lójú méjèèjì. Nítorí náà, bíi tàwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, àwa náà gbọ́dọ̀ máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ká sì ṣe é tọkàntọkàn títí tí òpin fi máa dé. (1 Kọ́r. 9:16; Mát. 24:14) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ tá a sì mọ nǹkan tá à ń ṣe bá a ti ń bá a nìṣó láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́?
2 Máa Ṣe Déédéé: Jèhófà, “Ọlọ́run ìṣòtítọ́” lẹni tó ṣeé fọkàn tán jù lọ. (Diu. 32:4) Gẹ́gẹ́ bí aláfarawé Ọlọ́run, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé àtijọ́, bíi Dáníẹ́lì, ‘sin Jèhófà láìyẹsẹ̀.’ (Dán. 6:20) Àwa náà gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ ká sì sin Jèhófà láìyẹsẹ̀, ní pàtàkì nínú iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Ìyẹn ń béèrè pé ká máa wàásù déédéé, ká sì máa ròyìn gbogbo ohun tá a bá ṣe lóde ẹ̀rí. Jèhófà ni Ọlọ́run àti Olùgbàlà, “ní pàtàkì ti àwọn olùṣòtítọ́.” (1 Tím. 4:10) Kéèyàn tó lè rí ìgbàlà ó gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́. (Fi wé Ìṣípayá 7:15.) Níwọ̀n bí ìṣòtítọ́ ti ṣe pàtàkì tó báyìí, a gbọ́dọ̀ pinnu láti máa ṣe déédéé lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
3 Akéde tó ń ṣe déédéé kì í jẹ́ kóṣù kan kọjá lọ láìwàásù. Ọ̀nà míì tó yẹ ká gbà máa fi hàn pé a jólóòótọ́ ni pé ká tètè máa fi ìròyìn wa sílẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì lóṣù. Bí ẹnì kan bá lọ sóde ẹ̀rí àmọ́ tí kò fi ìròyìn rẹ̀ sílẹ̀ níparí oṣù, a ò lè sọ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti fìṣòtítọ́ ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Tá a bá tètè ń fi ìròyìn wa sílẹ̀ níparí oṣù, tá a sì ń ròyìn ohun tá a ṣe lóde ẹ̀rí gẹ́lẹ́, ńṣe là ń fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́, pé a mọ ohun tá à ń ṣe, àti pé a jẹ́ aláápọn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sí Ọlọ́run. Èyí ń fi hàn pé ọkàn wa wà nínú iṣẹ́ ìwàásù náà, pé a mọrírì bó ti ṣe pàtàkì tó, pé à ń ṣe é lójú méjèèjì àti pé a fẹ́ ṣe iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti fẹ́. (Ìsík. 9:2, 11; 2 Tím. 4:2, 5) Ṣó o máa ń ṣe déédéé?
4 Àwọn Ohun Tó Lè Mú Ká Máa Ṣe Déédéé: Gbogbo ìgbà làwọn alàgbà máa ń rán wa létí pé ká máa wàásù déédéé. Jọ̀wọ́ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alábòójútó àti akọ̀wé ìjọ yín nípa títètè fi ìròyìn ohun tó o bá ṣe lóde ẹ̀rí sílẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì lóṣooṣù. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń ṣe ìfilọ̀ pé káwọn akéde fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn wọn sílẹ̀. Torí pé a jẹ́ onígbọràn àti olùṣe ọ̀rọ̀ náà, a mọ̀ pé ojúṣe wa ni láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kárí ayé, ètò Ọlọ́run ti fún àwọn akéde tí kò lè ṣe púpọ̀ mọ́ láǹfààní láti máa ròyìn ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nítorí ara wọn tó ti dara àgbà tàbí nítorí àìlera. Tá a bá jẹ́ aláìlera, ǹjẹ́ kò yẹ ká lo àkànṣe àǹfààní yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run.—Ják. 1:22.
5 Tá A Bá Ń Ṣe Déédéé Kò Ní Sí Aláìṣiṣẹ́mọ́: Bí akéde kan ò bá ròyìn lóṣù kan ó kéré tán, ó ti di akéde aláìṣedéédéé nìyẹn. Àmọ́, bí akéde kan ò bá ròyìn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ fún oṣù mẹ́fà gbáko, ó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ nìyẹn. Kò sí àníàní pé, ẹni tí kò bá ń ṣe déédéé lè di aláìṣiṣẹ́mọ́. Kò sẹ́ni tó máa fẹ́ kó sínú ewu tẹ̀mí yìí nínú wa. Láìka ìṣòro èyíkéyìí tó lè máa bá wa fínra sí, a fẹ́ máa ṣe déédéé, a fẹ́ jẹ́ aláápọn, a fẹ́ máa sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn, a sì fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ títí dé òpin.—Sm. 96:2.
6 Bá a bá ń ṣe déédéé, ìyẹn á jẹ́ ká nígbàgbọ́, ìgbàgbọ́ wa á máa lágbára, ìyẹn á sì máa dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí. Tá a bá tètè ń ròyìn iṣẹ́ ìsìn wa lóṣooṣù, ńṣe là ń fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti pé à ń fìtara ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wa níwájú Jèhófà ni pé ká ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti rí i dájú pé a jẹ́ akéde Ìjọba Ọlọ́run tó ń ṣe déédéé, ká sì jẹ́ kó mọ́ wa lára láti tètè máa ròyìn iṣẹ́ ìsìn wa.—Sm. 61:8; Lúùkù 10:17.