Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò lóṣù November: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. December: Ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí la máa lò. Bí onílé bá ní ọmọ, fún un ní ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. January: Ẹ lè lo ìwé èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ìwé míì tẹ́ ẹ tún lè lò bí àfidípò ni ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. February: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà la máa lò. Ìwé míì tẹ́ ẹ tún lè lò bí àfidípò ni ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà.
◼ A rọ gbogbo àwọn akéde tí kò bá tíì kọ ọ̀rọ̀ sínú káàdì DPA wọn pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Káàdì yìí ló máa dáàbò bo ẹ̀tọ́ tó o ní láti kọ ìfàjẹ̀sínilára. Àwọn alàgbà á pèsè ìrànlọ́wọ́ tó bá yẹ lórí èyí.—Wo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 2006.
◼ Kí ẹni tó bá fẹ́ fowó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé nípasẹ̀ ìwé sọ̀wédowó ní àpéjọ àgbègbè àtèyí tá a bá fẹ́ fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ “Watch Tower” sórí ìwé sọ̀wédowó náà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n máa sanwó náà fún. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kọ́ Watch àti Tower lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ni o.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti January 1, 2009, a ò ní máa lo ọ̀rọ̀ náà “alága àwọn alábòójútó” mọ́. Bá a ó ṣe máa pè é ni “olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà.”
◼ Kẹ́ ẹ tó dáwọ́ lé iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba èyíkéyìí, bóyá ẹ ṣẹ̀sẹ̀ fẹ́ kọ́ ọ ni o tàbí ẹ fẹ́ ṣàtúnṣe rẹ̀, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ kàn sí àwọn arákùnrin tó ń ṣètìlẹ́yìn fún Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ládùúgbò yín. Èyí tún kan ríra ilẹ̀ tàbí títa ilẹ̀. Àwọn arákùnrin tó ń ṣètìlẹ́yìn fún Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lè ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ láti ṣàwọn ìpinnu kan nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀, tó bá sì ṣeé ṣe kí wọ́n dẹni tó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.