Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa gbé yẹ̀ wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní December 29, 2008. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ November 3 sí December 29, 2008, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á sì darí rẹ̀ fún ogún [20] ìṣẹ́jú.
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Kí nìdí tó fi dá a ká máa gba àwọn èèyàn níyànjú “nítorí ìfẹ́”? (Fílém. 9) [be-YR ojú ìwé 266 ìpínrọ̀ 1 sí 3]
2. Báwo la ṣe lè mú káwọn èèyàn nígboyà? [be-YR ojú ìwé 268 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 269 ìpínrọ̀ 2]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
3. Lọ́nà wo ni lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí Títù gbà ‘dára lọ́pọ̀lọpọ̀ tó sì ṣàǹfààní’ fún wa lónìí? (Títù 3:8) [w91-YR 2/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 4]
4. Kí ló mú kí lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pétérù kọ bọ́ sákòókò? [w91-YR 3/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 2]
5. Ipa wo ni àwọn ìran tó wà nínú ìwé Ìṣípayá lè ní lórí wa? [w91-YR 5/1 ojú ìwé 21, ìpínrọ̀ 2]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
6. Bó ṣe wà nínú Títù 2:3, kí ló ṣeé ṣe kó mú kí Pọ́ọ̀lù so ọ̀rọ̀ náà “kì í ṣe afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́” mọ́ “bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n má ṣe di ẹrú fún ọ̀pọ̀ wáìnì”? [w94-YR 6/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 12]
7. Ǹjẹ́ ohun tí Bíbélì sọ pé Sátánì “ní ọ̀nà àtimú ikú wá” fí hàn pé ó lè dá ẹ̀mí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ légbodò? (Héb. 2:14) [w08-YR 10/15 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Títù, Fílémónì, àti Hébérù”]
8. Ta ni “ẹ̀dá ènìyàn olùdámájẹ̀mú” ti májẹ̀mú tuntun? (Héb. 9:16) [w08-YR 10/15 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Títù, Fílémónì, àti Hébérù”]
9. Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlááfíà, àwọn ìbéèrè wo la sì lè bi ara wa lórí ọ̀rọ̀ yìí? (Ják. 3:17) [w08-YR 3/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 18]
10. Kí ló túmọ̀ sí pé “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ”? (1 Jòh. 3:20) [w05-YR 8/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 19]