Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò lóṣù December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí onílé bá ní ọmọ, fún un ní ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. January: Ẹ lè lo ìwé èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ìwé míì tẹ́ ẹ tún lè lò bí àfidípò ni ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. February: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà la máa lò. Ìwé míì tẹ́ ẹ tún lè lò bí àfidípò ni ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
◼ A fẹ́ kẹ́ ẹ fi àkókò tẹ́ ẹ ó máa ṣèpàdé láti January 1, 2009 tó ẹ̀ka ọ́fíìsì létí. Bẹ́ ò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀ títí di báyìí, kí akọ̀wé ìjọ tètè ṣe bẹ́ẹ̀, kó lo fọ́ọ̀mù Congregation Meeting Information (S-5). A ti fi ẹ̀dà méjì fọ́ọ̀mù yìí ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ kí wọ́n lè lò ó. Ẹyọ kan ṣoṣo ni kẹ́ ẹ kọ ọ̀rọ̀ sí, kẹ́ ẹ sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì.