Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Inú wa dùn pé iye ìpadàbẹ̀wò tá a ròyìn lóṣù May, 2009 jẹ́ mílíọ̀nù kan, ogójì ọ̀kẹ́ àti igba ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [1,800,215]. Èyí fi ọ̀kẹ́ mẹ́fà ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàrin àti márùndínláàádọ́ta [127,045] ju iye ìpadàbẹ̀wò tá a ròyìn lóṣù May ọdún tó kọjá lọ. A tún darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó fi ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàjọ àti ọgọ́rin lé nírínwó [55,480], ju iye tá a darí lóṣù May ọdún tó kọjá.