Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Láàárín oṣù July sí November ọdún 2009, àwọn akéde ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún [689] láti ìjọ mẹ́tàléláàádọ́rin [73] ní Nàìjíríà ló lọ wàásù ní àwọn ìpínlẹ̀ tí a kò yàn fúnni. Wọ́n sì lo ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàafà àti irinwó dín méjì [51,398] wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ wíwá àwọn ẹni bí àgùntàn kiri. Àwọn ará wa tó lọ wàásù ní abúlé Ndi Ogbaga, ní ìpínlẹ̀ Ebonyi ròyìn pé: “Nígbà tí ọkùnrin kan wá sí ìpàdé ìjọ, ó sọ pé òun ti wá rí òtítọ́ tóun ti ń fi gbogbo ìgbésí ayé òun wá kiri. Ọkùnrin yìí kò sì pa ìpàdé kankan jẹ títí tá a fi kúrò ní abúlé náà.” Ǹjẹ́ o lè ṣètò ara rẹ, kó o bàa lè lọ wàásù ní ìpínlẹ̀ tí a kò yàn fúnni lọ́dún yìí?