Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí àwọn ọmọdé bá wà nínú ilé náà, kẹ́ ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. January: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ẹ fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. February: Ẹ lè lo ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé tàbí Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
◼ Ọjọ́ Sunday April 5 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2012, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀.