Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní October 31, 2011.
- 1. Kí nìdí tó fi yẹ ká rọ̀ mọ́ àwọn ìránnilétí Jèhófà? (Sm. 119:60, 61) [w00 12/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 3] 
- Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú Sáàmù 133:1-3? [w06 9/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 3] 
- Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ‘yẹ Dáfídì wò látòkè délẹ̀’ tó sì ‘díwọ̀n ìrìn àjò’ rẹ̀ àti ‘ìnàtàntàn rẹ̀ lórí ìdùbúlẹ̀’? (Sm. 139:1, 3) [w06 9/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 6; w93 10/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 6] 
- Ìṣòro wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lè wà nínú rẹ̀ tí Jèhófà á pèsè “ìtìlẹ́yìn” tàbí kí ó ‘gbé wọn ró’? (Sm. 145:14) [w04 1/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 11] 
- Kí ló mú kí ọkùnrin tí Òwe 6:12-14 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jẹ́ ẹni tí kò dára fún ohunkóhun? [w00 9/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 5 sí 6] 
- Kí nìdí tí ọlọ́gbọ́n èèyàn fi máa ń “tẹ́wọ́ gba àṣẹ”? (Òwe 10:8) [w01 7/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1] 
- Báwo ni ọlọ́gbọ́n àti òmùgọ̀ ṣe yàtọ̀ síra tó bá dọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe máa ń hùwà nígbà tí wọ́n bá fi ìwọ̀sí lọ̀ wọ́n tàbí tí wọ́n bá ṣe àríwísí wọn? (Òwe 12:16) [w03 3/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 3 sí 4] 
- Báwo ni níní èrò tó dáa ṣe máa ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti jẹ “àsè nígbà gbogbo”? (Òwe 15:15) [w06 7/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 6] 
- Báwo la ṣe lè dẹni tó “jèrè ọkàn-àyà,” ọ̀nà wo sì lẹni tó ṣe bẹ́ẹ̀ gbà “nífẹ̀ẹ́ ọkàn ara rẹ̀”? (Òwe 19:8) [w99 7/1 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 4] 
- Báwo ni ìfòyemọ̀ ṣe lè ṣàǹfààní fún ìdílé kan? (Òwe 24:3) [w06 9/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 11; be ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 1]